Ìgbanájẹ: Ìtọ́sọ́nà tí ó Rọrùn fún Àdúrà ÌgboyàÀpẹrẹ

Ignited: A Simple Guide for Bold Prayer

Ọjọ́ 1 nínú 6

Àdúrà jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì jù

Nínú Mátíù 9:37­–38, Jésù sọ wípé,

Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan. Nítorí náà,ẹ gbàdúrà sí Olúwaìkórè kí órán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.(YCB).”

“rán” ní èdè Gíríkì túmọ̀ sí kí á ti nǹkan jáde. Bí a ṣe dà ẹgbẹ́ Propel Women sílẹ̀ dá l'órí ẹsẹ Bíbélì yìí. Nítorí náà bí a ṣe ń wá láti tan iná àdúrà, a ó ṣe ohun tí Jésù pàṣẹ gan gan: a ó gbàdúrà sí Olúwa ìkórè láti rán àwọn alágbàṣe —láti tì wá jáde—sínú ìkórè. Ìkórè pọ̀. Ànfààní fún ìjọba Olórun láti gbòòrò ṣì wà níbí nísinsìyì. Kíni ohun pàtàkì tí yíò jẹ́ kí eléyìí sẹ̀lẹ̀? Àdúrà!

Àdúrà túmọ̀ sí kí á bá Ọlórun sọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ ìjíròrò tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ọkàn rẹ tàbí ní sísọ s:íta. O lè ṣẹlẹ̀ ní dídá wà tàbí ní àwùjọ. Ó lè ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ wa n'ílẹ̀, tàbí ẹgbẹgbẹ̀rún ẹsẹ̀ nínú atẹ́gùn. Ṣùgbọ́n ohun tí ó jọjú gan-gan nìyí: Bí a ṣe ń gbàdúrà, Ọlọ́run ń fetí síi, Ó ń sọ̀rọ̀, Ó sì ń dáhùn.

Ọlórun àgbáyé ń fẹ́ láti gbọ́ kí o sọ̀rọ̀. Kìí ṣe pé Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò àti pé Ó wá láti bá Òun sọ̀rọ̀ nínú àdúrà nìkan, ṣùgbọ́n Ó tún fi àdúrà wa papọ̀ sínú àwọn iṣé tí O ń ṣe ní àgbáyé!

Ní ibikíbi tí o bá wà, ipò kí ipò, kò sí bí o ṣe ní ànfààní tó — nínú ọjà, bíi ìyáálé-ilé, ọ̀gá Ilé-isẹ́, dókítà, olùkọ́, akékọ̀ọ́, agbẹjọ́rò, tàbí òṣèré — àdúrà ni ibi ìbẹ̀rẹ̀ tí iṣẹ́ Ọlọ́run àti iṣẹ́ rẹ nínú ayé yìí ti papọ̀. Bí a ṣe ń gbàdúrà, Ọlórun ti ṣe ìlérí láti mú àwọn òkè kúrò, mi àwọn ìpìlẹ̀, àti láti dé ibi ìkórè ńlá ti àwọn ènìyàn tí wọn kò ì tíì mọ̀ Ọ́. Ọlọ́run ti ṣe é pé kí àwọn àdúrà wa kéékèèké ṣe ìyàtọ̀ ńlà ní ìwọ̀n ìjọba Rẹ̀! Ọlọ́run ń yí ayé padà nípa agbára Rẹ̀ àti nípa ádúrà wa!

Àdúrà:

Olúwa, mo gbàdúrà nínú ọdún yìí kí n rí Ọ nínú agbára bí o ṣe ń mú àwọn ènìyàn wá s'ọ́dọ̀ Rẹ. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Rẹ nínú Mátíù 9:37-38, jẹ́ kí àwọn alágbàṣe pọ̀ síi, tí a tì sínú ìkórè ju bí ó ti ṣe wà tẹ́lẹ̀. Jẹ́ kí ọjọ́ iwájú jẹ́ àwọn ọjọ́ tí a óò mọ̀ fún ìkórè ńlá fún ògo Rẹ àti gbígbòòrò ìjọba Rẹ lórí ayé. Mo sì ṣe àdéhùn pẹ̀lú Rẹ nísinsìyí láti jẹ́ ara rẹ̀. Àmín.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Ignited: A Simple Guide for Bold Prayer

Àdúrà jé ẹ̀bùn, ànfàní nlá láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Bàbá wa lọ́run. Nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fa yìí, a ó ṣe àwárí ohun tí Jésù kọ́ wa nípa àdúrà àti a ó sì ṣí ọkàn wa payá láti gbàdúrà lóòrèkóòrè àti pẹ̀lú ìgboyà nlá.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christine Caine - A21, Propel, CCM fún ìpèsè ètò yìí. Tó bá fẹ́ mọ̀ sí, lọ sí https://www.propelwomen.org