Ìgbanájẹ: Ìtọ́sọ́nà tí ó Rọrùn fún Àdúrà ÌgboyàÀpẹrẹ

Gbígbọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
Kò sí ohun tí a lè fí ṣe àkàwé gbígbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọ̀nà kan láti gbọ́ ohùn Rẹ̀ ní nípa Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Róòmù 10:17 sọ fún wa wípé, ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (YBCV). Ṣùgbọ́n bí a bá fẹ́ rìn nípa ìgbàgbọ́ tí kì í sì ṣe nípa ti ara, bí a bá fẹ́ gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí a sì rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Rẹ̀, a ní láti tẹ̀síwájú nínú àdúrà kí a sì gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ní ohun púpọ̀ láti sọ fún wa. Àwọn ìgbésẹ̀ díẹ̀ tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyìí:
1. Ní Ìtara, Bí O Ṣe ń Retí
1 Sámúẹ̀lì 3 ṣe àkọsílẹ̀ ìtàn bí Sámúẹ̀lì ṣe kọ́ láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Kíni eléyíì túmọ̀ sí fún wa? Gẹ́gẹ́ bí i Sámúẹ̀lì, a lè má kọ́kọ́ dá ohùn Ọlọ́run mọ̀. Ó lè gbà wá ní àsìkò, sùúrù, àti ìtọ́sọ́nà àwọn ẹlòmíràn láti ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tí à ń gbọ́. Tẹ́tí sí I pẹ̀lú ìtara.
2. Wá Ibì Kan Fún un
Nínú gbogbo àkọsílẹ̀ Ìhìnrere, a rí i tí Jésù yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yín Rẹ̀ àti àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn láti wá ibi ìdákẹ́rọ́rọ́ kan láti gbàdúrà. Ó ṣe èyí nítorípé bí Ó tilẹ̀ jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, Ó tún jẹ́ ènìyàn pẹ̀lú. Ó d'ójúkọ irú àwọn ìpèníjà àti ìdààmú kannáà bí i tiwa, ìdí nìyìí tí Ó fi fi àpẹẹrẹ ìṣepàtàkì dídáwà láti gbàdúrà hàn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìgbàkúùgbà àti bí ó bá ṣe lè ṣe é sí, lo àwọn àkókò díẹ̀ láàrin ọjọ́ rẹ láti mú ọkàn rẹ parọ́rọ́ kí o sì gbàdúrà.
3. Dúróṣinṣin Nínú Rẹ̀
Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà déédéé ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí o sì tún rí i pé ó nira fún ọ láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run, má dẹ́kun. Máa tẹ̀ síwàjú. Máa ní ìgbàgbọ́. Máa gbàdúrà. Máa ṣe àṣàrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run títí tí yíó fi jẹ́ pé bí Ó bá s'ọ̀rọ̀, ìwọ yíó mọ̀ pé Óun ni! Nínú Jeremáyà 33:3, Ọlọ́run ṣe ìlérí wípé, “Képè mi, èmi yíó sì dá ọ lóhùn, èmi yíó sì fi ohun ńlá àti alágbára hàn ọ́ tí ìwọ kò mọ̀.” (YBC). Ìlérí tí ó tóó rántí nìyìí, kí a sì dúró rí i wípé ó wá sí ìmúṣẹ!
Prayer:
Ọlọ́run mọ yìn Ọ́ nítorípé O dára, Ó sì yẹ láti yìn. Láti ìran dé ìran àti láti ọdún dé ọdún, O kò yípadà. O jẹ́ olótìtọ́ sí àwọn ìlérí Rẹ. Ìfẹ́ Rẹ wà títí. Ọ̀rọ̀ Rẹ ṣe é sinmi lé. Máa wí, Olúwa, ìrànṣẹ́ Rẹ ń gbọ́. Àmín!
Nípa Ìpèsè yìí

Àdúrà jé ẹ̀bùn, ànfàní nlá láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Bàbá wa lọ́run. Nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fa yìí, a ó ṣe àwárí ohun tí Jésù kọ́ wa nípa àdúrà àti a ó sì ṣí ọkàn wa payá láti gbàdúrà lóòrèkóòrè àti pẹ̀lú ìgboyà nlá.
More