Irin Ń Lọ Irin: Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí® Ìtọ́ni nínú Májẹ̀mú LáéláéÀpẹrẹ

Ọjọ́ 5: Modekáì àti Esteri
Ṣáájú àti wo ìtàn Náómì àti Rúùtù a sìrí bí ìyá ọkọ ti lè kó ipa pàtàkì nípa títọ́ ìyàwó ọmọ ẹni sónà. Níbí yìí a rí bí Ọlọ́run ṣe leè lò wá láti kó pa nínú ayé àwọn ẹbí wa yòókù nítorí ìjọba Ọ̀run, pàápàá ọmọ ẹ̀gbọ́n ọkùnrin tàbí obìnrin (tàbí ọmọ tójẹ́ obìnrin) tó yàtọ̀.
Modekáì gbé inú Súsà, Páṣíà, ní àkókò ìgbèkùn àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ó bẹ̀rẹ̀ síí ṣe olùtọ́ni ọmọbìnrin arákùnrin bàbá rẹ̀ nítorí àwọn òbí rẹ̀ ti ṣàìsí, Esteri, ẹnití ó sì dàbíi ọmọbìnrin fún un. Ní bí ọ̀rọ̀ náà ṣeń lọ, a ríi bí ó ṣe wá jẹ́ ẹnití ó yẹ kí ó wà pẹ̀lú Esteri ní àkókò tí ó wọ̀, Esteri sì ni ẹnití ó yẹ láti dúró nínú àlàfo tí ó wà láàrin àwọn ènìyàn Ọlọ́run àti àwọn alátakò wọn “fún irú àkókò báyìí”!
Nínú àwọn orí mẹ́wàá ìwé Esteri, a rí bí ọmọbìnrin tí a kò lè lérò sí yìí ṣe gbérí tí ó sì di ayaba. Nítorí pé ó jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin tíkò sì ní ìrírí, àti pé ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ébérù tí wọ́n kó lẹ́rú, Esteri nílò ìtọ́sọ́nà tí àgbàlagbà tó ní òye lè ní.
Modekáì, alágbàtọ́ Esteri tọ́ ọ sọ́nà bí ó ṣe ń lọ, bí ó sì ṣe ń tẹ́tí síi, ó rí ojú rere níwájú àwọn tí ó yíi ká. Nígbàtí Ìgbìmọ̀ ibi dìde láti run gbogbo àwọn ọmọ Júù ilẹ̀ náà, Modekáì tọ́ Esteri nínú gbogbo ìgbésẹ̀ náà láti gbọ́kàn lé Ọlọ́run àti láti ṣìpẹ̀ àdúrà nítorí àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
Ọlọ́run dásíi! Ìtọ́ni Módékáì kò kàn yí ìgbésí ayé Esteri padà, ṣùgbọ́n ó tún yí odindi orílè-èdè padà pẹ̀lú. Ọlọ́run kò kàn pa àwọn ènìyàn Rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n Ó tún dáàbò bò wíwá Olúwa Jésù Kristi!
Òótọ́ bẹ̀ ni pé, a kò mọ oun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ṣe nígbàtí Ó ń tọ́ wa tí Ó sì ń lò wá láti rin ìrìn àjò Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí pẹ̀lú ẹlòmíràn. Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run fẹ́ràn ẹnìkọ̀kan Ó sì fẹ́ láti rí ìbá ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin kí wọ́n máa dàgbà sí ipa ìwà bíi Ọlọ́run tí ó ta yọ. Lákòókò kan náà, bí a ti ṣe ríi ní gbogbo àwọn àjọṣe pọ̀ Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí mí tí a ti wò, ó hàn gbangba dájú pé Ọlọ́run ń tẹ̀síwájú láti ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà àrà láti mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣe nínú ayé—Ó ún lo ìwọ àti èmi you fún ètò náà!
Àdúrà ni pé kí àgbéyẹ̀wò ìbáṣepọ̀ atọ́nisọ́nà Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí tinú Májẹ̀mú Àtijó ṣeé ìwúrí fún ọ láti bu omi rin àwọn tó yí ọ ká—níbití o ń gbé, ṣiṣẹ́, àti gbàdúrà!
_____
A fe dupe lowo Dean Ridings, onkowe Ìwé Àkọsílẹ̀ Àdúrà, Gbàdúrà!, fún kíkà Ẹ̀kọ́ yìí. Jọwọ ṣé àbèwò bákannáà, The Navigators.
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ òun wòye láti “sọ di ọmọ ẹ̀yìn tó n sọ di omo ẹ̀yìn,” láti tẹ̀lé ìlànà Jésù nínú Àṣẹ Ńlá (Mátíù 28:18-20)? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o leè ti ríi pé ó lè nira láti rí ẹni tí a kò bá fi ṣe olùtọ́ni sọ́nà fún ìgbésẹ̀ yí. Àpẹẹrẹ ta ni o leè tẹ̀lé? Báwo ni sí sọ ni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́? Ẹ jẹ́ kí a wo inú Májẹ̀mú Àtijó láti wo bí àwọn ọkùnrin márùn àti obìnrin ṣe bu omi rin ayé àwọn míràn, Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí ®.
More