Irin Ń Lọ Irin: Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí® Ìtọ́ni nínú Májẹ̀mú LáéláéÀpẹrẹ

Iron Sharpens Iron: Life-to-Life® Mentoring in the Old Testament

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ọjọ́ kẹta:Naomi and Ruth

Bí Ọlọ́run ṣe lo Mósè láti tọ́ Jóṣúà dàgbà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àwọn èèyàn Rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe lo Náómì láti bá Rúùtù ìyàwó ọmọ rẹ̀ rìn ní àkókò tí nǹkan ò rọgbọ fún un.

Àkọsílẹ̀ wọn wà nínú orí mẹ́rin ìwé Rúùtù. Ó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé àwọn Onídàájọ́ lẹ́yìn táwọn Hébérù dé Ilẹ̀ Ìlérí àmọ́ kí wọ́n tó di ọba wọn àkọ́kọ́. Ìyàn kan ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà, èyí sì mú kí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Élímélékì, Náómì ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin wọn méjì ṣí kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lọ sí Móábù.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n kó lọ síbẹ̀ ni àjálù kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí Elimelek kú. Àwọn ọmọkùnrin Náómì méjèèjì wá fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Móábù, àjálù tún ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọkùnrin méjèèjì kú. Ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà dúró ní Móábù, nígbà tí Rúùtù kejì tẹ̀ lé ìyá ọkọ rẹ̀ pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

Rúùtù, tó jẹ́ àjèjì ní Júdà, ilẹ̀ ọkọ rẹ̀, dúró ti Náómì, ó sì di olùkọ́ fún un. Tó o bá ronú nípa rẹ̀, àwọn méjèèjì ò lè yàtọ̀ síra. Ọ̀kan ti darúgbó, èkejì sì ṣì kéré. Ẹ̀yà, àṣà àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra.

Síbẹ̀, tá a bá ń ka ìtàn wọn, a máa rí i pé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ara wọn. A tún rí i tí Rúùtù bá Náómì dá májẹ̀mú kan, èyí tó ní nínú ìlérí tí Rúùtù ṣe tọkàntọkàn pé: "Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi. Ibi tí ìwọ bá kú ni èmi yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni a ó sin mi sí. Kí Olúwa ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ.”

Bí ìtàn náà ṣe ń lọ, Náómì ń bá Rúùtù rìn bí Rúùtù ṣe ń pàdé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bóásì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ ọn. Ìtọ́sọ́nà rẹ̀ yóò yọrí sí ìgbéyàwó Rúùtù àti Bóásì. Rúùtù máa di ìyá ńlá Dáfídì Ọba, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ìyá ńlá Jésù, Mèsáyà!

Ìtàn wọn jẹ́ ká rí i pé àjọṣe tó wà láàárín ìran àti ìran máa ń ṣe àwọn méjèèjì láǹfààní. A nílò ara wa gan-an! Ìgbésí Ayé-sí-Ìgbésí Ayé ni wípé, olúkúlùkù ń pín ìgbésí ayé rẹ̀ pẹ̀lú èkejì Bí àpẹẹrẹ Náómì àti Rúùtù ṣe fi hàn, irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ lè wà nínú ìdílé wa pàápàá!

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Iron Sharpens Iron: Life-to-Life® Mentoring in the Old Testament

Ǹjẹ́ òun wòye láti “sọ di ọmọ ẹ̀yìn tó n sọ di omo ẹ̀yìn,” láti tẹ̀lé ìlànà Jésù nínú Àṣẹ Ńlá (Mátíù 28:18-20)? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o leè ti ríi pé ó lè nira láti rí ẹni tí a kò bá fi ṣe olùtọ́ni sọ́nà fún ìgbésẹ̀ yí. Àpẹẹrẹ ta ni o leè tẹ̀lé? Báwo ni sí sọ ni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́? Ẹ jẹ́ kí a wo inú Májẹ̀mú Àtijó láti wo bí àwọn ọkùnrin márùn àti obìnrin ṣe bu omi rin ayé àwọn míràn, Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí ®.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Navigators fún ìpèsè èètò ẹ̀kọ́ ìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.navigators.org/youversion

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ