Irin Ń Lọ Irin: Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí® Ìtọ́ni nínú Májẹ̀mú LáéláéÀpẹrẹ

Iron Sharpens Iron: Life-to-Life® Mentoring in the Old Testament

Ọjọ́ 2 nínú 5

Day 2: Mósè àti Jóṣúà

Mósè jẹ́ ọkùnrin tí Ọlọ́run ya sọ́ tọ̀ ní àsìkò pàtàkì Nínú ìtàn àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ọlọ́run lò ó láti mú àwọn Hébérù jáde kúrò ní Íjíbítì àti níkẹyìn dé ibi àbáwọlé ilẹ̀ ìlérí náà

Mósè yan àwọn ọkùnrin méjìlá, tó dúró fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá, láti yẹ ilẹ̀ náà wò. Lára wọn ni Joṣua ọmọ Nuni, lati ẹ̀ya Efraimu (Numbers 13:16). Òun àti Kélẹ́bù tó jẹ́ mẹ́ńbà àwọn méjìlá náà mú ìròyìn rere kan wá tó fi ìdánilójú hàn pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n lè gba ilẹ̀ ìlérí náà!

Àjọṣe tí Mósè ní pẹ̀lú Jóṣúà jálẹ̀ àwọn ìwé Ẹ́kísódù àti Númérì tan ìmọ́lè sí pàtàkì ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láàárín àwọn ìran, ìgbésí ayé idàmọràn. (Fún Ìmọ̀ tó jinlẹ̀, wo Exodus 24:13; 32:17; 33:11; àti Numbers 11:25-29; 13:1-14:10.) 

Jálẹ̀ ìrìn àjò ogójì ọdún tí àwọn Hébérù gbà la aginjù Sínáì kọjá, Ọlọ́run lo Mósè láti fi kọ́ ọkùnrin kan tí ó “sanra” ẹni tí óOlódodo, Rááyè, àti kọẹkọ.Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, nípasẹ̀ ìtọ́nisọ́nà ìgbésí-ayé, Mósè gbé aṣáájú àwọn Hébérù tí ó tẹ̀ lé e dìde. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín Jóṣúà yóò ṣamọ̀nà àwọn èèyàn Ọlọ́run sínú ilẹ̀ ìlérí. 

Kíni ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti ara àpẹẹrẹ tí Mósè? Fi tàdúràtàdúrà ronú nípa wíwá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́ kan ní àyíká ipa rẹ. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fi ẹnì kan tó sún mọ́ Ọlọ́run tó sì sún mọ́ ọn hàn Mósè, bóyá Ọlọ́run yóò fi irú “eni” kan náà hàn ọ́. Àwọn wo ni àwọn Ọmọ Ọlọ́run ọkùnrin àti obìnrin fún ọjọ́ ọ́la? Bóyá Ọlọ́run yóò lò ọ́ láti gbé aṣáájú fún ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àní ti ìjọ tàbí ti iṣẹ́ ìsìn parachurch dìde ní ọjọ́ iwájú!  

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Iron Sharpens Iron: Life-to-Life® Mentoring in the Old Testament

Ǹjẹ́ òun wòye láti “sọ di ọmọ ẹ̀yìn tó n sọ di omo ẹ̀yìn,” láti tẹ̀lé ìlànà Jésù nínú Àṣẹ Ńlá (Mátíù 28:18-20)? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o leè ti ríi pé ó lè nira láti rí ẹni tí a kò bá fi ṣe olùtọ́ni sọ́nà fún ìgbésẹ̀ yí. Àpẹẹrẹ ta ni o leè tẹ̀lé? Báwo ni sí sọ ni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́? Ẹ jẹ́ kí a wo inú Májẹ̀mú Àtijó láti wo bí àwọn ọkùnrin márùn àti obìnrin ṣe bu omi rin ayé àwọn míràn, Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí ®.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Navigators fún ìpèsè èètò ẹ̀kọ́ ìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.navigators.org/youversion

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ