Irin Ń Lọ Irin: Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí® Ìtọ́ni nínú Májẹ̀mú LáéláéÀpẹrẹ

Ọjọ́ Kìíní: Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì
Ábúráhámù fún wa ní ọ̀kan lára àwọn àpẹẹrẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó ti pẹ́ jù lọ nínú Májẹ̀mú Láéláé.Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tẹ̀ lé e kúrò ní ìlú Úrì, ó sì tẹ̀ lé e lọ sí ilẹ̀ tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.
Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ábúráhámù ti jẹ́ olùkọ́ nípa fífi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Lọ́ọ̀tì ń wo bí Ábúráhámù ṣe pàdé rẹ̀, tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀, tó sì ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Ó rí bí Ábúráhámù ṣe kọ́ pẹpẹ fún Olúwa tí ó fara han òun. Lọ́ọ̀tì rí i pé Ábúráhámù gbára lé Ọlọ́run gan-an, òun náà sì ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.
Bí Olúwa ti ń mú kí àwọn méjèèjì ní aásìkí, àkókò kan dé tí ilẹ̀ náà kò lè gba agbo ẹran wọn, màlúù wọn àti àgọ́ wọn, nítorí náà, wọ́n ní láti pínyà. Ábúráhámù fi inú rere sọ fún Lọ́ọ̀tì pé kó kọ́kọ́ yan ibi tóun fẹ́ kọ́kọ́ máa gbé, Ábúráhámù sì kó lọ sí ibòmíì.
Kíyè sí bí Ábúráhámù ṣe ń ṣọ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ó gba Lọ́ọ̀tì sílẹ̀ nígbà tí ìṣòro dé bá a, ó sì bẹ̀bẹ̀ tọkàntọkàn fún Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ nígbà tí ìṣòro míì tún dé.
Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú àjọṣe yìí nípa ìtọ́ni èèyàn? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, má ṣe fojú kéré ipa tí àpẹẹrẹ tìrẹ fúnra rẹ ní! Àpẹẹrẹ rẹ máa ń jẹ́ olùkọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn, àgàgà àwọn tó o jọ ń rìn.
Èkejì, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Àkókò tá a máa lò pẹ̀lú wọn kò ní pọ̀ tó, a sì gbọ́dọ̀ fi wọ́n sí ààbò Ọlọ́run fún àkókò gígùn. Nígbà míì, wọ́n lè ṣe àwọn ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu, tí wọ́n tiẹ̀ lè yọrí sí àjálù pàápàá (Jẹ́nẹ́sísì 19:8, 33, 34). Bákan náà, a kì í jẹ́ kí wọ́n kúrò lọ́kàn wa pátápátá. A múra tán láti jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run lò láti sọ òtítọ́ sínú ìgbésí ayé wọn, láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé gígùn, tó sì méso jáde nínú Olúwa.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ òun wòye láti “sọ di ọmọ ẹ̀yìn tó n sọ di omo ẹ̀yìn,” láti tẹ̀lé ìlànà Jésù nínú Àṣẹ Ńlá (Mátíù 28:18-20)? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o leè ti ríi pé ó lè nira láti rí ẹni tí a kò bá fi ṣe olùtọ́ni sọ́nà fún ìgbésẹ̀ yí. Àpẹẹrẹ ta ni o leè tẹ̀lé? Báwo ni sí sọ ni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́? Ẹ jẹ́ kí a wo inú Májẹ̀mú Àtijó láti wo bí àwọn ọkùnrin márùn àti obìnrin ṣe bu omi rin ayé àwọn míràn, Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí ®.
More