Mordekai si jade kuro niwaju ọba, ninu aṣọ ọba, alaro ati funfun, ati ade wura nla, ati ẹ̀wu okùn ọ̀gbọ kikuná, ati elese aluko; ayọ̀ ati inu didùn si wà ni ilu Ṣuṣani. Awọn Ju si ni imọlẹ, ati inu didùn, ati ayọ̀ ati ọlá. Ati ni olukulùku ìgberiko, ati ni olukuluku ilu nibikibi ti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, awọn Ju ni ayọ̀ ati inu-didùn, àse, ati ọjọ rere. Ọ̀pọlọpọ awọn enia ilẹ na si di enia Juda; nitori ẹ̀ru awọn Ju ba wọn.
Kà Est 8
Feti si Est 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Est 8:15-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò