Irin Ń Lọ Irin: Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí® Ìtọ́ni nínú Májẹ̀mú LáéláéÀpẹrẹ

Ọjọ́ 4: Dáfídì àti Jònátànì
Irú ìrẹ́pọ̀ t'ó wà láàrin Dáfídì àti Jònátànì tún jẹ́ irú àwòrán mìrán-àn t'ó ń ṣe àpẹẹrẹ bí ìtọ́nisọ́nà Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí ṣe lè rí.
Sọ́ọ̀lù Ọba ni ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì, Jónátánì sì ni ọmọ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jé pé ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, díẹ̀díẹ̀, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ síí k'ẹ̀hìn sí Ọlọ́run ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹsẹ̀ ìdílé rẹ̀ bí ọba múlẹ̀. Ara ìfẹsẹ ìdílé múlẹ̀ ni ìlàkàkà rẹ̀ láti ríi pé Jónátánì yóò jọba lẹ́hìn òun nígbà t'ó bá yá.
Síbẹ̀ èyí kìí ṣe èètò Ọlọ́run. Dípò bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ti darí wòlíì t'ó ń jẹ́ Sámúẹ̀lì, láti fi òróró yan ọ̀dọ́mọkùnrin darandaran Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò rọ́pò Sọ́ọ̀lù. Dáfídì jẹ́ "ẹni ọkàn Ọlọ́run." Ó ṣe ni láàánú pé Ọba Sọ́ọ̀lù yàtọ̀ sí èyí. Nítorí náà, owú mú kí Sọ́ọ̀lù máa lé Dáfídì kiri lójú méjèèjì pẹ̀lú èté láti pa á kí ọ̀nà lè ṣí sílẹ̀ fún Jònátànì láti gba ìtẹ́ kí ó sì jọba lẹ́hìn òun. (Wo 1 Samueli 1-31.)
Láàrin gbogbo rúdurùdu yìí, nnkan àìròtẹ́lẹ́ kan ṣẹlẹ̀: Dáfídì àti Jònátànì di kòríkòsùn ara wọn; “ọkàn Jonatani, ọmọ Saulu fà mọ́ Dafidi lọpọlọpọ ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀.” Kò sí ìdíje, kò sí ìfòyà pé ọ̀kan nínú wọn máa ba ọ̀rẹ́ náà jẹ́: àwọn méjèèjì dúró lórí ìpinnu pé àwọn máa dúró ti ara àwọn ni lọ́wọ́ b'ó ti lè wù kó rí.
Káàkiri nínú Bíbélì ni a ti rí irú ìpè sí ìbáṣepọ̀ tó ní ànfààní fún tọ̀tún tòsì báyìí. “A rí i nínú òwe méjì: "Ẹni t'ó ní alábákẹ́gbẹ́ púpọ̀ lè ṣègbé, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tó súnmọ́ ni ju ọmọ ìyá lọ", àti, “Bí irin ti ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.” (Ìwé Òwe 18:24; 27:17).
Láti inú ọ̀rẹ́ Dáfídì àti Jònátànì a kọ́ nípa bí ó ti ṣe pàtàkì kí ènìyàn ní "olùgbọ̀wọ́" tòótọ́. Ní tòótọ́, bí Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ti kọ, ènìyàn méjì sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ (Ìwé Oníwàásù 4: 9-12) àti pé nígbà tí Ọlọ́run bá wà nínú ìbáṣepọ̀, "okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀” (ẹsẹ 12).
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ òun wòye láti “sọ di ọmọ ẹ̀yìn tó n sọ di omo ẹ̀yìn,” láti tẹ̀lé ìlànà Jésù nínú Àṣẹ Ńlá (Mátíù 28:18-20)? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o leè ti ríi pé ó lè nira láti rí ẹni tí a kò bá fi ṣe olùtọ́ni sọ́nà fún ìgbésẹ̀ yí. Àpẹẹrẹ ta ni o leè tẹ̀lé? Báwo ni sí sọ ni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́? Ẹ jẹ́ kí a wo inú Májẹ̀mú Àtijó láti wo bí àwọn ọkùnrin márùn àti obìnrin ṣe bu omi rin ayé àwọn míràn, Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí ®.
More