I. Sam 20:41-42

I. Sam 20:41-42 YBCV

Bi ọmọdekunrin na ti lọ tan, Dafidi si dide lati iha gusu, o si wolẹ, o si tẹriba lẹrinmẹta: nwọn si fi ẹnu ko ara wọn li ẹnu, nwọn si jumọ sọkun, ekini keji wọn, titi Dafidi fi bori. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ma lọ li alafia, bi o ti jẹ pe awa mejeji ti jumọ bura li orukọ Oluwa, pe, Ki Oluwa ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin iru-ọmọ mi ati lãrin iru-ọmọ rẹ lailai. On si dide, o si lọ kuro: Jonatani si lọ si ilu.