Rut 4:14-17

Rut 4:14-17 YBCV

Awọn obinrin si wi fun Naomi pe, Olubukun li OLUWA, ti kò fi ọ silẹ li ainí ibatan li oni, ki o si jẹ́ olokikí ni Israeli. On o si jẹ́ olumupada ẹmi rẹ, ati olutọju ogbó rẹ: nitori aya-ọmọ rẹ, ẹniti o fẹ́ ọ, ti o san fun ọ jù ọmọkunrin meje lọ, li o bi i. Naomi si gbé ọmọ na, o si tẹ́ ẹ si owókan-àiya rẹ̀, o si di alagbatọ́ rẹ̀. Awọn obinrin aladugbo rẹ̀ si sọ ọ li orukọ, wipe, A bi ọmọkunrin kan fun Naomi; nwọn si pè orukọ rẹ̀ ni Obedi: on ni baba Jesse, baba Dafidi.