Ìràpadà Ìlépa-ỌkànÀpẹrẹ

Dreams Redeemed

Ọjọ́ 6 nínú 7

"Kíni o fẹ́?" Ọkọ mi àtijọ́ bérè ìbérè yìí bí ìgbeyàwó wa se ńfi orí sọ́pán. "Mo fẹ́ kí o se ohun tí ọkùnrin kankan ò se rí... Mo fẹ́ kí o jà fún mi." ohùn mi ńgbọ̀n pẹ̀lú ẹkún.

Nígbà díẹ̀ si, bí mo se ńla ìpèníjà dídá omo tọ́, mo ní òye wípé Ọlọ́run ńbèrè ìbérè yìí lọ́wọ́ mi, lẹ́ẹ̀kansi àti lẹ́ẹ̀kansi. "Kíni o fẹ́?" Fún ọ̀pọ̀ odún, mi ò le dáhùn ìbérè yìí tí Ọlọ́run ńbèrè lọ́wọ́ mì. Njẹ́ ohun tí mo fẹ́ fibẹ́ẹ̀ se pàtàkì? Mò ńrò.

Mo fi gbogbo ìpòngbẹ àti ìfẹ́ ọkàn mi pamọ́ sẹ́hìn ohun tí àwọn ènìyàn ṣábà má nso, tó dùn gbọ́ létí, "Ìfẹ tìre ni kó sẹ, kìí se tèmi".

Bíótilẹ̀jẹ́pé yíyọ̀nda ara sí Ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ohun tí ón dára, ó gbà mí ní àkókò kí ntó wá rí wípé Ọlọ́run ò sí lẹ́yìn àìnàtán- Ófẹ́ ọkàn mi. Ọlọ́run ò mú wa bíi ẹrú tí o yíò kàn máa dáhùn sí àse ọ̀ranyàn àti ìnilára, sùgbọ́n ó mú wa bíi ọmọ obìnrin àti ọkùnrin tí yíò dáhùn Sí nípa ìbárẹ́ àti ìb ásepọ̀.

Mo ti gbọ́ rí wípé, Ìpòngbẹ dára, Ó jẹ́ ìró ohun ìyanu tí ó nbọ̀."

Ọlọ́run bìkítà nípa ohun tí a fẹ́. Ó bìkítà nípa ìpòngbẹ ọkàn wa. Tí a bá jọ̀wọ́ ara fún, Ó ma ńlo àkókò ìdúró láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ rinlẹ̀ ṣí àti láti fà wá mọ́ra sí ọ̀dọ̀ rẹ bí a se fi àwọn ìpongbẹ wa hàn n. Tí a ba ńsọ àwọn ìfẹ́ okàn wa pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí kò já sí pé gbogbo ohun tí a fẹ́ ni a ó rí gbà. Ọlọ́run kìí se àlálùpàyídà. Sùgbọ́n bí a se ńbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa ohun tí a gbèrò lọ́kàn yíò mú wa súnmọ ṣí.

Ìwọ wo bí yíò se rí kí á ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ọkọ tàbí aya tí a kò le sọ nípa èrò ọkàn tàbí ohun tí a fẹ́ tọkàntọkàn fún? Mo rò pé a ó ní ìmọ̀lára bíi pé kò sí àjọsepọ̀ láàrin wa, ìbárẹ́ yì ò sì ní jinlẹ̀ rárá. Bí a se ńpín ohun tí a gbèrò àti ìfẹ́ ọkàn wa, yíò má jẹ́ kí ìbárẹ́ wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn jinlẹ̀ sí.

Nípa ti tèmi, lẹ́yìn àwọn ọdún díẹ̀ tí mi ò nàn tán nípa ìfẹ́ mì láti ní ìdílé titèmi, níparí mo sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún Ọlọ́run. Mo fẹ́ lọ́kọ lẹ́ẹ̀kan sí. Mo fẹ́ ẹni tí mo lè má sọ nípa ìfẹ́ ọkàn mi, ojúse àti ìpèníjà, àti ohun tí ó mú inú mi dùn, àti ohun tí ó mú mi sukún fún.

Àkókò ìdúró tẹ̀síwájú. Nínú èyí, Ọlọ́run tẹ̀síwájú ó fọwọ́kàn mí. Ó fi ìdúró yì kọ́ mi nípa ìbárẹ́ pàsípààrọ̀ àti kíni ìbárẹ́ tòótó jẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí kò léwu. Mo tún dàgbà sókè nínú ìgbàgbọ́ mi wípé Ọlọ́run dára. Àti wípé ìwà Rẹ̀ seé gbẹ́kẹ̀lẹ́. Èrò Rẹ̀ sí mi dára. Ọlọ́run kọ́mi wípé àyídàyídà nínú ayé mi kò le yí àwọn òtítọ́ yì padà. Ó kọ́ mi láti dúrólóri àwọn òtítọ́ yì, pẹ̀lú nígbàtí mi ò rò pé mo rí ẹ̀rí wọn.

Kíni o fẹ́?

Nínú gbogbo Ìwé Mímọ́, Jésù ńbèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ àwọn tí ó pàdé ní orísìrísì ọ̀nà. Mo sì nígbàgbọ́ wípé ó ńbèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Mo gbà ọ́ níyànjú wípé kí o sàwárí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí kí o sì sọ fún. Ọlọ́run séé gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú ìpòngbẹ ọkàn wa.

Nípa Ìpèsè yìí

Dreams Redeemed

Kíni a lè ṣe nígbà tí àwọn ìlépa wa bá dàbí èyí tó jìnà réré tàbí bíi ìgbà tí a kò bá lè bá a láíláí? Lẹ́yìn tí mo borí ìlòkulò àti ìbanilọ́kànjẹ́, pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn ti ìkọ̀sílẹ̀, mo ti dojúkọ ìbéèrè yìí lẹ́ẹ̀kànsi. Bóyá ò ń ní ìpèníjà ti àjálù tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ìbànújẹ́ ti àkókò ìdádúró, ìlépa Ọlọ́run fún ìgbésí-ayé rẹ ṣì wà láàyè! Ọ̀rẹ́, àkókò tó láti lá àlá lẹ́ẹ̀kansi.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Harmony Grillo (I Am A Treasure) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: http://harmonygrillo.com