Ìràpadà Ìlépa-ỌkànÀpẹrẹ

Ni owurọ Ọjọ Satide kan ti o wuyi, m o wo ọmọbinrin mi ọdun mẹta ti o ladun bi o ti n sun ni alaafia. Mo ti n murasilẹ lati ji, nitoriti mo gbèro ati yàálẹnu pẹlu ounjẹ àárọ ayanfẹ rẹ ati láti mu u jade lo wo fiimu pelu ijade wara-didi.
Mo rọra gba irun kuro ni iwaju orii rẹ mo si bẹrẹ si ṣe itọju ẹrẹkẹ rẹ. “La'ju omode olóòrun,” Mo wi si leti ni kẹlẹkẹlẹ.
Lojiji, awọn ọwọ ati ẹsẹ rẹ fẹsẹmulẹ bi o ti fò sinu ikanra ibinu. “Raraaaa! Emi ko fẹ lati ji, ”o pariwo kikan. Oju rẹ kekere bi ti angẹli yen, si yipo o funjunpo, èrèkè re si pon wa.
Okan mi jinmi. Yato si fifọ mi nipasẹ ibinu rẹ, edun okan nla lo je pe a ko le ni ọjọ igbadun ti mo ti pè'ro rè fun.
Ọmọbinrin mi fẹ lati wa lori ibusun, ni ibi ti o wa. Oorun re tu lara. Ifihan egan rẹ jẹ ki o padanu nkan nla kan. Ko si ọna ti nn o fi mu lọ ijade ọjọ pataki wa, nko le fi se esan iwa ibinu naa. Ti o ba mọ ohun ti mo ni lokan fun oun, yoo ha ti huwa lọna ti o yatọ bi? Ti o ba gbẹkẹle eto mi, ti o ba gbẹkẹle emi , nje idahun rè o bá yatọ bi?
Mo ròó boya mi o ti padanu ohunkan ri ti Ọlọrun ni ni ipamọ fun mi, nitori mo ti gbadun jinna itura ipo ti mo wa. Aseju idojukọ ohun ti emi fẹ.
Nigbamiran, ohun ti a fẹ ni a fẹ, ati pe a ro pe ohun ti a nilo ni. Ṣugbọn ti a ba ni igbẹkẹle gaan pe Ọlọrun dara ati wípe ero Rẹ dara, a ó tẹtisi. A óo tẹle-paapaa nigbati o ba da awọn ero ti ara wa rú ti o si mu wa kuro nnu ipo itunu wa. Paapaa nigbati o tumọ si pe o to akoko lati jawo ninu awọn ibatan, awọn iwa, tabi irora ti o ti mu wa sẹhin.
Igbẹkẹle wa ni ipilẹ igbagbọ - lati ni igbagbọ ninu Ọlọrun ni lati gbẹkẹle eto Rẹ, botilèje pe a ko loye rẹ. O tun jẹ ipilẹ ti erongba Ọlọrun fun igbesi aye wa. Ni awọn akoko to dàbi ẹni pe igbesi aye bi mo ti mọ sí ti yapa patapata, igbẹkẹle ninu Ọlọrun fun mi ni aaye to mùlè lati duro.
"Ji, olufẹ. La oju rẹ. Wa pẹlu mi. Mo ni ohun iyanu ti mo gbero fun ọ. Lati le ni iriri ohun ti mo ni ni ipamọ fun ọ, o ko le duro si ibiti o wa. O to akoko lati sún siwaju, ifẹ mi. "
Mo gbagbọ pe Ọlọrun n pe iwọ ati emi sinu ero ti o jẹ iyalẹnu ju awọn ero inu wa ti a le mọ lọ. Ọkan ti yio ni imúpadàbọsipo ati iràpada gbogbo ohun ti o ti sọnu ati ti won ji lọ. Ibeere naa ni pe, nje awa yoo gbeke wa le E to lati tẹle?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Kíni a lè ṣe nígbà tí àwọn ìlépa wa bá dàbí èyí tó jìnà réré tàbí bíi ìgbà tí a kò bá lè bá a láíláí? Lẹ́yìn tí mo borí ìlòkulò àti ìbanilọ́kànjẹ́, pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn ti ìkọ̀sílẹ̀, mo ti dojúkọ ìbéèrè yìí lẹ́ẹ̀kànsi. Bóyá ò ń ní ìpèníjà ti àjálù tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ìbànújẹ́ ti àkókò ìdádúró, ìlépa Ọlọ́run fún ìgbésí-ayé rẹ ṣì wà láàyè! Ọ̀rẹ́, àkókò tó láti lá àlá lẹ́ẹ̀kansi.
More