ÌhùwàsíÀpẹrẹ

Ẹ̀mímímọ́ Wà Pẹ̀lû àti ní Inú Wa
... ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí máa darí ìgbé-ayé yín, tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣẹ.. Gàlátíà 5:16 NLT
Láti bíi ọjọ́ mẹ́fà, a ti ń ṣe àgbéyẹ̀wò ìṣesì tí ó ń wá nípa ìmoore, ìrẹ̀lẹ̀, oore-ọfẹ, òtítọ́-inú, ìrètí, àti ìgbékẹ̀lé. Ṣùgbọ́n ìṣesí wa lè yí bìrìpó, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹǹkan ni ó sì maá ń ṣe okùnfà rẹ̀, tí ó fi mọ́ àwọn ohun tí a kò le ṣe ìkáwọ́ wọn.
A jẹ́ ènìyàn tí kò pé n'íye, tí ó ń tiraka láti gbé ìgbé-ayé wa ní ọ̀nà tí yíó bu ọlá fún Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n a ṣì maá ń kanra, j'owú ẹlòmíràn, bẹ̀rù ọjọ́ iwájú, a sì ń kùnà láti fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí ẹlòmíràn. Nítorínáà báwo ní a ṣe lè dàbí Krístì, ẹni tí ó tẹ̀lé Ọlọ́run ní pípé? Kìí ṣe pé a ní àpẹrẹ pípé nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Jésù nìkan, a tún ní àǹfààní sí Ẹ̀mí Rẹ́ tí Ó ń gbé nínú wa, gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe ìlérí.
Ẹ̀mímímọ́ ń gbé inú ọmọlẹ́yìn Jésù kọ̀ọ̀kan, Ó ń tọ́ wa, Ó sì ń ṣe ẹ̀dá Krístì nínú wa. A kò dá nìkan wà nínú ìrìnàjò yìí. Ọ̀rọ̀ tí Jésù lò ní Jòhánù14 láti ṣe àpèjúwe Ẹ̀mímímọ́ nipárákílítì, ọ̀rọ̀ tí ó túmọ̀ sí olùtùnú, alágbàwí, àti ẹni tí ń dúró tí ni.
Ẹ̀mímímọ́ kò kàn wà pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n ó wà nínú wa.
Eléyìí kò túmọ̀ sí pé o kò níí ní èrò òdì tàbí gbàgbé nípa Ọlọ́run ní àwọn ààyè pàtàkì kan, kí o sì f'èsì pẹ̀lú ìṣesí tí kò dára. Ó túmọ̀ sí pé Ó wà fún wa, Ó ń ṣiṣẹ́ nínú wa àti pẹ̀lú wa ní ojoojúmọ́.
Gbàdúrà:Ọ̀lọ́run, bí mo ṣe ń lọ nínú ìgbòkègbodò mi, ran ìṣesí mi lọ́wọ́ láti fi Ẹ̀mí Krístì tí ó wà ní inú mi hàn. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbọ́ràn sí Ẹ̀mímímọ́ bí O ṣe ń darí mi ní ojoojúmọ́. Mo dúpẹ́ fún ìfẹ́ tí O ní sí mi àti fún Ẹ̀mí Rẹ tí O fi fún mi. Ní orúkọ Jésù, àmín.
Ṣe àwàrí àwọn àdúrà fún okun, ìrètí, ìdààmú ọkàn àti àníyàn.
Nípa Ìpèsè yìí

Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.
More