ÌhùwàsíÀpẹrẹ

Attitude

Ọjọ́ 6 nínú 7

Ìrètí àti Ìgbẹ́kẹ̀lé

Jésù! tí Ó sọ ẹ̀rù wa di ayọ̀,
Tí ó mú ìbànújẹ́ tán;
Orin ni ní etí ẹlẹ́ṣẹ̀,
Ìyè àti ìlera.
—Charles Wesley

Ìwé Agbédègbẹyọ̀ nípa Ìmọ̀ Ọgbọ́n-orí ti Stanford ṣe àpèjúwe ìgbẹ́kẹ̀lé bí i “ìṣesí tí a ní sí ènìyàn tí a rò pé ó jẹ́ olóòótọ́.” Bí a bá lo àpèjúwe yìí, a kò jẹ ayòpa bí a bá sọ pé ìṣesí Charles Wesley àti ọ̀pọ Krìstíẹ́nì sí Jésù kún fún ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó kún fún ìrètí.

Síbẹ̀, ọjọ́ iwájú lé dàbí ibi ẹ̀rú àti ibi àìmọ̀. A kò le mọ̀ dájú ohun tí yíó ṣẹlẹ̀ ní ìṣèjú tí ó kàn. Tàbí ohun tí àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí, tàbí adarí wa yíó ṣe. A lè ní ètò láti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga, kí ó má sì sí ìrànlọ́wọ́ owó. Tàbí àwọn ààtò nípa ìrìnàjò ìgbafẹ́ lè polúkúrúmuṣu mọ́ wa lọ́wọ́ látàrí ìjì tí a kò retí. Tàbí ohun tí ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.

À ń gbé nínú ayé tí kò rọrùn láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé. Dípò kí á gbẹ́kẹ̀lé ẹlòmíràn, a lè gbìyànjú láti darí àwọn àbájáde fúnraawa, kí á kọ láti fi ara jìn, kí á sì fà ṣẹ́yìn láti fí àìpéníye wa hàn. Tàbí kí a yan ọ̀nà èké míràn láti ṣe ìkáwọ́: àìbìkítà. A lè rò pé bí a kò bá gbìyànjú, tí a kò gbẹ́kẹ̀lé, tàbí bìkítà, nígbà náà a kò lè já wa kulẹ̀.

Gbígbé ayé láìní ìgbẹ́kẹ̀lé lè dàbi ẹnipé ó dára, ṣùgbọ́n o mú u ṣòro láti tẹ̀lé Jésù.

Ọlọ́run fi gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀ tán ènìyàn. Ó fí ọkàn tán ọdọ́mọbìrin kan àti gbẹ́nàgbẹnà kan láti jẹ́ òbí ọmọ bíbí Rẹ kanṣoṣo. Jésù sọ fún àwọn apẹja kí wọ́n fi iṣẹ́ òòjọ́ wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé Òun. Lẹ̀yìn náà Ó pe Pétérù láti gbẹ̀kẹ̀lé Òun tó láti rìn lórí omi. Ó pe àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ láti fi ọkan tán ara wọn tó láti rìn ìrìnàjò ní méjìméjì láì mú ìpààrọ̀ aṣọ lọ́wọ́ tàbí oúnjẹ. Lákòtán, Jésù fi ọkàn tán wa, awa ara Rẹ̀, láti ní ìfẹ́ ayé yìí gẹ́gẹ́ bí Òun ti ní.

Nígbà mìíràn tí ìjákulẹ̀ bá mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Ọlọ́run yinjẹ, tí ìṣesí rẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn, rántí pé ìgbẹ́kẹ̀lé ń pè fún ìrètí. Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn onígbàgbọ́ tí ó wà ní Róòmù nígbà tí ó wà nínú túbú, ó rán wa létí pé ìwà rere ni ó ń mú kí á ní ìrètí, èyí sì máa ń wá láti inú ìfaradà, tíí ṣe àbájáde ìjìyà..

Gbàdúrà: Ọlọ́run, bí mo ṣe ń la ìjì ayé kọjá, ràn mí lọ́wọ́ láti fi èrò àti ìṣesí mi sí inú Jésù. Jẹ́ kí ojú mi wà lára ohun tí ó tọ́, tí ó ni ọlá, tí í ṣe òdodo, tí ó mọ́, tí ó dára, tí ó yẹ fún ìyìn, tí ó pé àti tí ó ní ìròyìn rere. Kọ́ mi láti ní ìfaradà, ìwà ọmọlúwàbí àti ìrètí. Ní orúkọ Jésù, àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Attitude

Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ