ÌhùwàsíÀpẹrẹ

Attitude

Ọjọ́ 4 nínú 7

Bíborí Ìlara

Kíni ìdí rẹ̀ tí a fi máa ń ṣe ìlara ìdùnnú àti ohun rere tí ó jẹ́ ti àwọn ẹlòmíràn? Ìdí ni pé a jẹ́ agbéraga; àwa nìkan ni a fẹ́ẹ́ jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn, ọrọ̀, ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ gbogbo ayé!—Ẹni-ọ̀wọ̀ John Vianney

Ǹjẹ́ ìṣesí rẹ maá ń yípadà bí àwọn ènìyàn kan bá yọjú? Èrò àti ìmọ̀lára wa nípa àwọn ohun tàbí ènìyàn kan a máa ní ipa ní orí ìhùwàsí wa, nítorí náà kò ṣe àjèjí pé àwọn ènìyàn kan lè máa mú wa bínú ju àwọn mìíràn lọ. Dípò tí à bá fi máa ronú nípa àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run fi fún wa, a lè wo ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ẹlòmíràn, kí á sì sọ pé, "Ó wù mí kí èmi náà wà ní irú ipò yẹn.” Ẹ̀mí ìlara ni èyí.

Ìlara ni ìfẹ́ láti ní ohun tí ẹlòmíràn ní, ó sì lè yọrí sí ìyípadà eléwu nínú ìwà wa, títí kan ìbínú.

Ìlara jẹ́ kókó inú ọ̀kan lára àwọn àkàwé Jésù tí ó gbajúmọ̀ jùlọ, ìyẹn ni àkàwé ọmọ onínàákúnàá. Nínú ìtàn yìí, ọ̀dọ́mọkùnrin kan ń kánjú láti gba ọrọ̀ bàbá rẹ̀ ó sì béèrè fún ogún-ìní rẹ̀ kí àkókò tóó tó. Ní àkókò àti nínú àṣà ìbílẹ̀ ìgbà yìí, irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé ó wù ú kí bàbá òun ti kú. Ìlara lè mú irú ìwà yìí wá—kí a máa wo ènìyàn bíńtín ní ìdiwọ̀n ohun ìní àti àṣeyọrí wọn.

Ọmọkùnrin náà fi ọrọ̀ tí ó ṣe ìlara rẹ̀ ṣ'òfò nípa gbígbé ìgbésí ayé ìjẹkújẹ. Ní ìgbà tí ó rí i pé òpin tí dé fún òun àti wípé yíó sàn fún òun láti jẹ́ ẹrú nínú ilé bàbá òun, ó padà, t'òun ti ìtìjú. Àmọ́, ohun kan wà tí ó ṣe àjèjì nínú ìtàn Jésù. Dípò tí bàbá náà ìbá fi lé ọmọ rẹ̀ padà, ó sáré lọ bá a, ó dì mọ́ ọ, ó sì ṣe àsè ńlá láti kí i káàbọ̀ sí ilé.

Ìlara kò ì tíì parí iṣẹ́. Ọ̀dọ́kùnrin náà ní ẹ̀gbọ́n kan tí ó ń wo gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Inú bí ẹ̀gbọ́n yìí gan-an látàrí àánú tí bàbá rẹ̀ fi hàn sí àbúrò rẹ̀ débi pé ó bu ẹnu àtẹ́ lu bàbá rẹ̀, kò sì wá sí ibi ayẹyẹ náà. Ní ìgbà tí a bá gba ìlara láàyè láti ba ìwòye wa nípa àwọn ẹlòmíràn jẹ́, a lè fi àìmọ̀kan pa igi dí ọ̀nà oore-ọ̀fẹ́ ọ̀pọ̀ yanturu ti Baba wa ọ̀run.

Ṣùgbọ́n oore-ọ̀fẹ́ tó. Ní ìgbà tí ẹ̀mí ìlara bá rú jáde nínú wa, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó ní ipa lórí ìṣesí wa. Bàbá inú ìtàn Jésù yìí gba oore-ọ̀fẹ́ àti ọ̀pọ̀ yanturu láàyè láti ní ipa lórí ìṣesí rẹ̀ sí ọmọ rẹ̀, àwa náà sì lè ṣe bákan náà, láìka ẹni tí ó ṣ'òro fún wa láti ní ìfẹ́ sí sí. Bàbá wa ọ̀run ní ìfẹ́ waÓ sì tún ní ìfẹ́ ẹni tí à ń ṣe ìlara rẹ̀pẹ̀lú ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kannáà. Báwo ni a ṣe lè borí ìlara? Nípa gbígba àti pípín oore-ọ̀fẹ́.

Tani ìwọ yíó na ọwọ́ oore-ọ̀fẹ́ sí ní ọ̀sẹ̀ yìí? Àwọn ọ̀nà wo ni o ti níílò oore-ọ̀fẹ́?

Gbàdúrà:Ọlọ́run, mo dúpẹ́ pé ìbùkún Rẹ wà lórí gbogbo ènìyàn. Bí ilara bá wà ní ọkàn mi, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jáwọ́ nínú rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fẹ́ràn Rẹ sí i fún ọkàn Rẹ tí ń búkún ni, dípò kí n máa ṣe àríwísí inú rere Rẹ sí àwọn ẹlòmíràn. Jẹ́ kí n mọ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ tí ó jinlẹ̀ fún mi kí n sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. Ní orúkọ Jésù, àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Attitude

Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ