ÌhùwàsíÀpẹrẹ

Attitude

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ǹjẹ́ Oníkùnsínú Ni Ọ́?

Ọlọ́run sọ wípé kí á máa dúpẹ́ nínú ohun gbogbo nítorípé nípa bẹ́ẹ̀ ní a ṣe lè la ohun gbogbo kọjá. —Anne Voskamp

Ǹjẹ́ o ti ṣe àkíyèsi pé ò ń kùn? Bóyá ò ń kùn nípa ìlànà ìjọsìn ìjọ rẹ, ẹni tí alábàágbépọ̀ rẹ dìbò fún, tàbí bí olùkọ́ àgbà rẹ ṣe ń dáni lẹ́kọ̀ọ́. Èyí fi ìṣesí rẹ hàn ní àwọn àkókò yẹn—ọ̀nà ìrònú rẹ tàbí bí ǹǹkan ṣe rí ní ara rẹ. Àpóstélì Pọ́ọ̀lù mọ ewu tí ó wà nínú ìkùnsínú, ó kọ́ wà nínú Fílípì 2 láti “ṣe ohun gbogbo láísí ìkùnsínú tàbí àríyànjiyàn.”

Kíni ìdi tí Pọ́ọ̀lù fi kàn ní ipá pé kí o máṣe sì ìkùnsínú? Ní àkọ́kọ́, ronú bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe wà títí, tí ó pọ̀ rékọjá, tí ó sì tó fún gbogbo ènìyàn. Láti òórọ̀ di alẹ̀,Ọlọ́run ń b'ójú tó wà. Nípasẹ̀ Jésù, ìbùkún Ọlọ́run tí ó gá jù, a lè ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. Bí èyí kò bá sì tó, Ó tún pè wà láti jẹ́ alábaṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Òun nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ pínpín ìfẹ́ rẹ̀ káàkiri ayé.

Ní báyìí ronú nípa ìkùnsínú àti ìkanra—ǹjẹ́ wọ́n dọ́gba pẹ̀lú ìbùkún àti ìpè Ọlọ́run ní ayé wa? Báwo ní a ṣe lè ká ẹsẹ̀ ìkúnsínú tí ó ti rápálá wọlé n'ílẹ̀? Nípa ìmoore.

Níní òye ohun tí à ń dúpẹ́ fún ni àtẹ̀yìnwá, lọ́wọ́lọ́wọ́, àti ní ọjọ́ iwájú a máa tọ́ ayé wa sí ọ̀nà, a sì máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ rírì ìbùkún tí Ọlọ́run fún wa. A lè rí ìṣesí yìí nínú Jésù ní Hébérú 12. Ní ojú ikú ní orí àgbélébùú, Jésù fi ojú sí ayọ̀ tí ó wà ní iwájú rẹ̀: ọjọ́ iwájú pẹ̀lú wa, àwa ènìyàh tí Ó wá gbàlà.

Fún wa, níní ọkàn ìmoore lè jẹ́ àkókò àṣàrò kékeré ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ọjọ́ wa nípa ohun tí à ń dúpẹ́ fún. Tàbí bóyá kí a máa ka ọ̀rọ̀ onísáàmú ní ìgbà gbogbo pé:

Òní ni ọjọ́ tí Olúwa dá, ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn. Sáàmù 118:24 YCE

Ìwàpẹ̀lẹ́ tíí ṣe ìṣe ti ẹ̀mí lè rán wá lọ́wọ́ láti dẹ́kun àti máa kùn—a lè yan ìmoore àti ìtẹ́lọ́rùn dípò pé kí á máa ra àwọn ǹǹkan léraléra tí a rò pé dára sí i.

Ní ìgbà tí a bá rántí àwọn ohun tí à ń dúpẹ́ fún, pàápàá jùlọ ayọ̀ tí ó wà ní iwájú nípasẹ̀ Krístì, ìṣesí wa á túnbọ̀ dàbíi ti Jésù.

Gbàdúrà:Ọlọ́run, O ṣeun fún ìbùkún Rẹ ìgbà gbogbo nínú ayé mi, láti orí àwọn ǹǹkan kékéèké dé orí ìdílé àti àwón ọ̀rẹ́ mi, dé orí ẹ̀bùn tí ó ga jù gbogbo rẹ̀ lọ: rírán ọmọ Rẹ láti fún mi ní ìyè kíkún. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ tí ó wà ní iwájú mi. Ẹ̀mímímọ́, jọ̀wọ́ ṣe ẹ̀dá ọkàn Krístí ní inú mi. Ní orúkọ Jésù, àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Attitude

Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ