ÌhùwàsíÀpẹrẹ

Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Ọlọ́run
Kí ènìyàn tóó jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere, ó ní láti kọ́kọ́ fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́ Krístì pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ńlá.—Basil of Caesarea (Básílì ará Kesáríà)
Ní inú ẹsẹ Bíbélì ti òní, Pọ́ọ̀lù yá ọ̀rọ̀ orìn kan lò láti ṣe àkàwé ohun tí ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá jọ. Jésù, bí Ó tilẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run, rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ wá sí inú ayé, Ó sì di ènìyàn. Ó kú ní orí àgbélégbúú fún wa, Ó fi ara Rẹ̀ rúbọ̀ nítorí ìfẹ́ ńla Rẹ̀ sí wa. Jésù ṣe àpẹẹrẹ ìṣesí ìrẹ̀lẹ̀ tí ó ga jú fún wa—ṣùgbọ́n bàwo ni àwa náà ṣe lè ṣe èyí?
Pọ́ọ̀lù ń yànnàná àfiwé tí ó wà láàárín àwọn Krìstìẹ́nì, èyí tí ó máa ń wáyé ní ìgbà míràn látàrí ìlànà ẹ̀sìn tí ó yàtọ̀ sí ara wọn tàbí nítorí ipò tí wọ́n wà ní àwùjọ. Ọ̀pọ̀ nínú wa ṣì ń d'ojúkọ irú ìṣòro kan náà lónìí. Ǹjẹ́ ó ti ṣe àkíyèsi rí pé o bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò òdì nípa ara rẹ ní ìgbà tí o bá ń fi ara rẹ wé ẹlòmíràn? Ǹjẹ́ o ti hùwà sí ẹnìkan ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn nítorí pé ó ní owó jù ọ́ lọ tàbí pé búrùjí rẹ̀ kéré sí tìrẹ? Ǹjẹ́ ó máa ń t'ojú sú ọ bí àwọn ènìyàn bá yàtọ̀ sí ọ nínú ìrísí, ìwà tàbí ọ̀rọ̀ wọn?
Ní ìgbà tí a bá ń fi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn, ó rọrùn láti gbàgbé bí olúkúlùkù ṣe ní iye l'órí tó lójú Ọlọ́run. Ní ìwòye Ọlọ́run, gbogbo ènìyàn ni a dá ní àwòrán Rẹ̀, tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí pátápátá, tí Jésù sì tóó kú fún. Ní ìgbà tí a bá ń bá àwọn ẹlòmíràn ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí mìíràn, a kò fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù fi lélẹ̀ ṣe ìwà hù, èyí yíó sì fa ìbànújẹ́ àti ìpalára tí kò yẹ nínú ìbáṣepọ̀ wa.
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lè yí ohun gbogbo padà. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ iyì àwọn ẹlòmíràn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n rí ara wọn bí Jésù ṣe rí wọ́n. Ní sàn-án-sàn-án, fífi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn lè jẹ́ títẹ́ ésẹ̀ dúró díẹ̀ láti bá alábàṣiṣẹ́pọ̀ rẹ ṣe àwàdà, rírí i dájú pé gbogbo àwọn tí ó wà ní ìdìí tábìlì ni wọ́n mọ ara wọn lọ́ọ́kọ̀kan, títọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ rẹ, tàbí jíjókòó ti ẹnìkan tí ó dá wà. Ó lè túmọ̀ sí gbígba àdúrà ìbùkún fún àwọn tí ẹ́ jọ ń ṣe ìfàńfá, àti wíwá ọ̀nà láti ní òye èrò wọn. Jésù ka ẹ̀mí wa sí pàtàkì tó láti fi ẹ̀mí tirẹ̀ lélẹ̀ fún wa, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀lé ìṣísẹ̀ rẹ̀, kí á sì wo àwọn tí ó wà ní áyìíká wa gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ní iye lórí—tí ó yẹ fún àkókò, ọlá àti àkíyèsí wa.
Gbàdúrà: Ọlọ́run, O dá ènìyàn ní àwòrán ara Rẹ. Gbogbo wa ni a ṣe iyebíye ní ojú Rẹ tó bẹ́ẹ̀ tí O gbé ìgbé-ayé Rẹ—tí O sì fi ẹ̀mí Rẹ lélẹ̀—láti gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àìmọ̀kan ara wa. Ràn mí lọ́wọ́ láti fi irú ìrẹ̀lẹ̀ mérīyírí Rẹ ṣe ìwà hù ní ojoojúmọ́ ayé mi, kí O sì tọ́ mi láti fí irú ìfẹ kannáà ti O ní sí mi hàn fún àwọn ẹlòmíràn. Ní orúkọ Jésù, àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.
More