ÌhùwàsíÀpẹrẹ

Attitude

Ọjọ́ 5 nínú 7

Jésù Sọkún

Olúkúlùkù ohun ni àkókò wà fún ... ìgbà sísọkún ...Ìwé Oníwàásù 3:1, 4 YBCV

Àwọn àkókò kan wà tí ó jẹ́ pé ìṣesí rere kọ́ ló kàn. Àṣà lè mú àwọn ìdí tí a fi gbọ́dọ̀ ní ìṣesí rere dá wa lójú, kí a mú èrò ibi inú wa kúrò kí a sì fi ọkàn sí ohun rere—ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó yẹ kí ọ̀rọ̀ wa àti èrò-ara wa jẹ́ rere nìkan nígbàtí a tí mọ́ pé àrùn jéjẹrẹ yìí yíó yọrí sí ikú? Tàbí pé ìkọ̀sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó yìí yío ṣẹlẹ̀ dandan? Tàbí ọmọ ẹni wà lójú ikú? Tàbí bí rògbòdìyàn ayé ẹni má ní òpin?

Nínú arò, Jésù fi ìṣesí rere tí yíó dára hàn wá bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kìí ṣe nínú ohun rere.

Arò jẹ́ ìkáàánú tàbí ọ̀fọ̀ àtọkànwá. Ó le má dùn mọ́ 'ni tàbí kí ó bà'ni lára mu, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìdáhùn tí ó tọ́ sí ìrora àti ọgbẹ́-ọkàn tí ó jọ pé kò ṣe é wò. Ní pàtó, bí títẹ̀lé Jésù bá pè fún gbígbé ìṣesí Rẹ̀ wọ̀ ní inú ohunkóhun tí a bá dojúkọ, a jẹ́ pé yíyẹra fún arò kò dára tó fún ìdàgbàsókè ẹ̀mí wa.

Ó wọ́pọ̀ kí á fi àríyà, ẹ̀rín akọ, oògùn, ọtí-líle, tàbí ẹ̀sìn àfibojú lásán bo ìbànújẹ́ ọkàn wa m'ọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ní àwọn àkókò kan ohun tí ó dára jù tí a lè ṣe ni kí a ṣ'arò: kí a gba ìbànújẹ́ náa láàyè, kí a sì sọ ọ́ fún Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn t'ọkàntọkàn wa, kí a gba Ọlọ́run láàyè láti wò ọgbẹ́-ọkàn wá sàn.

Jésù ṣe arò. Jésù sọkún. Bóyá ìdí tí Jòhánù 11:35 fi jẹ́ ẹsẹ tí ó kúrú jùlọ nínú Bíbélì ni pé nígbàtí ọkan lára àwọn ọ̀rẹ̀ tímọ́tímọ́ ẹni bá kú, kò sí ọ̀rọ̀ tí a fí lè ṣe àkàwé irú ìhà tí a lè kọ sí i. Jésù sọkùn lórí ikú ọ̀rẹ̀ rẹ̀ Lásárù—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ó tí fẹ́ jí Í dìde kúrò nínú òkú.

Ní orí àgbélébú, Jésù fí oju sí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú Rẹ̀, èyítí ó ràn án lọ́wọ́ láti ní ìṣesí oore-ọfẹ àti ìdáríjì bí Ó ṣe dáríji àwọn tí ó ṣe ikú pa Á. Síbẹ̀, ní àkókò náà, Jésù ṣì képe Baba Rẹ̀ ní ohun àrò, “Èéṣe tí Ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

Ọlọ́run kìí ṣe òńrorò tí Ó máa ń wo ìrora ìṣẹ̀dá Rẹ̀ láti òkè láì bìkítà. Jésù fúnra rẹ̀ fi hàn pé a lè béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ní àkókò tí ó nira jùlọ fún wa. Ọlọ́run ní àwọ̀ ènìyàn ṣ'ọ̀fọ̀ òfò ẹ̀dá ènìyàn. Jésù kò dáwọ́ ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó ní nínú ìfẹ́ Bàbá Rẹ̀ dúró, bẹ́ẹ̀ ni kò dẹ́kun ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìyanu fún Lásárù; Ó kàn ń fi ìbànújẹ́ àti ìrora ọkàn rẹ̀ hàn ní ọ̀nà tí ó bá a mu wẹ́kú nípasẹ̀ omijé Rẹ̀. Ó ṣ'ọ̀fọ̀ ní ìgbà àdánù àti ìrora.

Àwọn àdánù tàbí ipò wo ni ó yẹ kí á ṣ'ọ̀fọ̀ fún? Báwo ni o ṣe lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù nípa fífi ẹ̀dùn ọkàn hàn fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, ìdílé rẹ, àti ìjọ rẹ?

Gbàdúrà: Ọlọ́run, O jẹ Ọlọ́run tí ń sọkún. Ọlọ́run tí ń ṣe ìtọ́jú àwọn ẹ̀dá rẹ tí O sì ń gbà wọ́n ní ìyànjú láti ṣ'ọ̀fọ̀. Ràn mí lọ́wọ́ láti mọ irú èrò-ara tí mò ń là kọjá, kí n mọ ìrora mi, kí ń sí sọkún arò. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbékẹ̀lé Ọ láàrín àwọn èrò-ara yìí, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. Ní orúkọ Jésù, àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Attitude

Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ