YouVersion Logo
Search Icon

Ìfihàn Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìfáàrà sí Ìwé Ìfihàn ti Johanu
Ìsọ̀rí ńlá méjì ni ìwé pàtàkì yìí ní, àkọ́kọ́ jẹ́ lẹ́tà sí ìjọ Ọlọ́run méje ní agbègbè Asia (1–3). Ìsọ̀rí kejì jẹ́ oríṣìíríṣìí ìran tó dá lórí ayé àti inúnibíni àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ìpadàbọ̀ Kristi, ìdájọ́ ìkẹyìn, ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún, àti ìjọba Ọlọ́run (4–22). Àwọn ìran wọ̀nyí ń sọ nípa ìparun tó ń bọ̀ wá sórí ayé, àti ìfarahàn Jesu Kristi ní àkókò náà. Ó tún sọ nípa àwọn tí a pa nítorí ẹ̀rí Kristi àti àwọn ẹni mímọ́ tí a ṣe inúnibíni sí ní ayé. Ìran náà tẹ̀síwájú nípa ìbínú Satani sí àwọn ọmọ Ọlọ́run, ìkórè ayé, ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run, èrè àti ìjìyà lẹ́yìn ìdájọ́ ìkẹyìn.
Ìwé yìí fi Jesu hàn bí ẹni tí a kẹ́gàn, ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run tí a pa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Ìrètí gbogbo Kristiani ni pé, ní ọjọ́ kan, ohun gbogbo yóò padà bọ́ sí ipò, Ọlọ́run ni yóò jẹ́ ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. A ó nu omijé nù, ikú, ìbànújẹ́, ẹkún àti ìrora yóò lọ pátápátá (21.4). Ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí wà fún gbogbo Kristiani ní ìgbà gbogbo.
Kókó-ọ̀rọ̀
Ìran tí ó kọ́ wáyé 1.1-20.
Lẹ́tà méje sí àwọn ìjọ Ọlọ́run méje 2.1–3.22.
Ìran Ọlọ́run àti ọ̀dọ́-àgùntàn 4.1–5.14.
Èdìdì méje ti ìdájọ́ 6.1–8.5.
Ìpè méje ti ìdájọ́ 8.6–11.19.
Ìran ohun ti ayé àti ohun ti ọ̀run 12.1–14.20.
Ọpọ́n ìdájọ́ méje 15.1–16.21.
Ìdájọ́ àgbèrè àti Babeli 17.1–19.21.
Òpin ìran àti ìran tí ń bọ̀ 20.1–22.21.

Currently Selected:

Ìfihàn Ìfáàrà: BMYO

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in