YouVersion Logo
Search Icon

Mat 6

6
Ẹ̀kọ́ nípa Ìtọrẹ Àánú
1 Ẹ kiyesi ara ki ẹ máṣe itọrẹ anu nyin niwaju enia, ki a ba le ri nyin: bi o ba ri bẹ̃, ẹnyin ko li ère lọdọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun.
2 Nitorina nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe fun fère niwaju rẹ, bi awọn agabagebe ti nṣe ni sinagogu ati ni ita, ki nwọn ki o le gbà iyìn enia. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na.
3 Ṣugbọn nigbati iwọ ba nṣe itọrẹ ãnu rẹ, máṣe jẹ ki ọwọ́ òsi rẹ ki o mọ̀ ohun ti ọwọ́ ọtún rẹ nṣe;
4 Ki itọrẹ ãnu rẹ ki o le wà ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ, on tikararẹ̀ yio san a fun ọ ni gbangba.
Ẹ̀kọ́ nípa Adura
(Luk 11:2-4)
5 Nigbati iwọ ba ngbadura, máṣe dabi awọn agabagebe; nitori nwọn fẹ ati mã duro gbadura ni sinagogu ati ni igun ọ̀na ita, ki enia ki o ba le ri wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na.
6 Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ̀ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkùn rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.
7 Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ máṣe atunwi asan bi awọn keferi; nwọn ṣebi a o ti itori ọ̀rọ pipọ gbọ́ ti wọn.
8 Nitorina ki ẹnyin máṣe dabi wọn: Baba nyin sá mọ̀ ohun ti ẹnyin ṣe alaini, ki ẹ to bère lọwọ rẹ̀.
9 Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.
10 Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye.
11 Fun wa li onjẹ õjọ wa loni.
12 Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa.
13 Má si fà wa sinu idẹwò, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin.
14 Nitori bi ẹnyin ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin.
15 Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba fi ẹ̀ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ki yio si fi ẹ̀ṣẹ ti nyin jì nyin.
Ẹ̀kọ́ nípa Ààwẹ̀ Gbígbà
16 Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na.
17 Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ;
18 Ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.
Ìṣúra ní Ọ̀run
(Luk 12:33-34)
19 Ẹ máṣe tò iṣura jọ fun ara nyin li aiye, nibiti kòkoro ati ipãra ibà a jẹ, ati nibiti awọn olè irunlẹ ti nwọn si ijale:
20 Ṣugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipãra ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale.
21 Nitori nibiti iṣura nyin bá gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.
Ìmọ́lẹ̀ Ara
(Luk 11:34-36)
22 Oju ni fitila ara: nitorina bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ ni yio kún fun imọlẹ.
23 Ṣugbọn bi oju rẹ ba ṣõkùn, gbogbo ara rẹ ni yio kun fun òkunkun. Njẹ bi imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ba jẹ́ òkunkun, òkunkun na yio ti pọ̀ to!
Ọlọrun ati Ohun Ìní Eniyan
(Luk 16:13; 12:22-31)
24 Ko si ẹniti o le sìn oluwa meji: nitori yala yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio faramọ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin ko le sìn Oluwa pẹlu mamoni.
25 Nitorina mo wi fun nyin, Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ẹmí nyin ohun ti ẹ ó jẹ, ati fun ara nyin ohun ti ẹ o fi bora. Ẹmí kò ha jù onjẹ lọ? tabi ara ni kò jù aṣọ lọ?
26 Ẹ sá wò ẹiyẹ oju ọrun; nwọn kì ifunrugbin, bẹ̃ni nwọn kì ikore, nwọn kì isi ikójọ sinu abà, ṣugbọn Baba nyin ti mbẹ li ọrun mbọ́ wọn. Ẹnyin kò ha san jù wọn lọ?
27 Tani ninu nyin nipa aniyàn ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀?
28 Ẽṣe ti ẹnyin sì fi nṣe aniyan nitori aṣọ? Kiyesi lili ti mbẹ ni igbẹ́, bi nwọn ti ndàgba; nwọn kì iṣiṣẹ, bẹ̃ni nwọn kì irànwu:
29 Mo si wi fun nyin pe, a ko ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ ninu gbogbo ogo rẹ̀ to bi ọkan ninu wọnyi.
30 Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ bẹ̃, eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu iná lọla, melomelo ni ki yio fi le wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin oni-kekere igbagbọ?
31 Nitorina ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, Kili a o jẹ? tabi, Kili a o mu? tabi, aṣọ wo li a o fi wọ̀ wa?
32 Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn keferi nwá kiri. Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ̀ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi.
33 Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ̀; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin.
34 Nitorina ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ọla; ọla ni yio ṣe aniyan ohun ara rẹ̀. Buburu ti õjọ to fun u.

Currently Selected:

Mat 6: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy