YouVersion Logo
Search Icon

Mat 4

4
Satani Dán Jesu Wò
(Mak 1:12-13; Luk 4:1-13)
1NIGBANA li a dari Jesu si ijù lati ọwọ́ Ẹmi lati dán a wò lọwọ Èṣu.
2Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a.
3Nigbati oludanwò de ọdọ rẹ̀, o ni, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ ki okuta wọnyi di akara.
4Ṣugbọn o dahùn wipe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Enia kì yio wà lãyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá.
5Nigbana ni Èṣu gbé e lọ soke si ilu mimọ́ nì, o gbé e le ṣonṣo tẹmpili,
6O si wi fun u pe, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, li ọwọ́ wọn ni nwọn o si gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta.
7Jesu si wi fun u pe, A tún kọ ọ pe, Iwọ ko gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.
8Èṣu gbé e lọ si ori òke giga-giga ẹ̀wẹ, o si fi gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn hàn a;
9O si wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ó fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o si foribalẹ fun mi.
10Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Pada kuro lẹhin mi, Satani: nitori a kọwe rẹ̀ pe, Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mã sìn.
11Nigbana li Èṣu fi i silẹ lọ; si kiyesi i, awọn angẹli tọ̀ ọ wá, nwọn si nṣe iranṣẹ fun u.
Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ ní Galili
(Mak 1:14-15; Luk 4:14-15)
12Nigbati Jesu gbọ́ pe, a fi Johanu le wọn lọwọ, o dide lọ si Galili;
13Nigbati o si jade kuro ni Nasareti, o wá ijoko ni Kapernaumu, eyi ti o mbẹ leti okun li ẹkùn Sebuloni ati Neftalimu:
14Ki eyi ti a wi lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe,
15Ilẹ Sebuloni ati ilẹ Neftalimu li ọ̀na okun, li oke Jordani, Galili awọn keferi;
16Awọn enia ti o joko li òkunkun ri imọlẹ nla; ati awọn ti o joko ni ibi iku ati labẹ ojiji rẹ̀ ni imọlẹ là fun.
17Lati igbana ni Jesu bẹ̀rẹ si iwasu wipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ.
Jesu Pe Apẹja Mẹrin
(Mak 1:16-20; Luk 5:1-11)
18Jesu nrin leti okun Galili, o ri awọn arakunrin meji, Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitori nwọn jẹ apẹja.
19O si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia.
20Nwọn si fi àwọn silẹ lojukanna, nwọn sì tọ̀ ọ lẹhin.
21Bi o si ti ti ibẹ lọ siwaju, o ri awọn arakunrin meji, Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, nwọn ndí àwọn wọn; o si pè wọn.
22Lojukanna nwọn si fi ọkọ̀ ati baba wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.
Jesu Ń Ṣiṣẹ́ láàrin Ọpọlọpọ Eniyan
(Luk 6:17-19)
23Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagogu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia.
24Okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo Siria ká; nwọn si gbé awọn alaisàn ti o ni onirũru àrun ati irora wá sọdọ rẹ̀, ati awọn ti o li ẹmi èṣu, ati awọn ti o nsinwin, ati awọn ti o li ẹ̀gba; o si wò wọn sàn.
25Ọpọlọpọ enia si tọ̀ ọ lẹhin lati Galili, ati Dekapoli, ati Jerusalemu, ati lati Judea wá, ati lati oke odò Jordani.

Currently Selected:

Mat 4: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy