YouVersion Logo
Search Icon

JOBU 1

1
Satani Dán Jobu Wò
1Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jobu; ó ń gbé ilẹ̀ Usi, ó jẹ́ olódodo ati olóòótọ́ eniyan, ó bẹ̀rù Ọlọrun, ó sì kórìíra ìwà burúkú. 2Ó bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta. 3Ó ní ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan, ẹgbẹẹdogun (3,000) ràkúnmí, ẹẹdẹgbẹta (500) àjàgà mààlúù, ẹẹdẹgbẹta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ọpọlọpọ iranṣẹ; òun ni ó lọ́lá jùlọ ninu gbogbo àwọn ará ìlà oòrùn.
4Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa lọ jẹ àsè ninu ilé ara wọn. Olukuluku wọn ní ọjọ́ àsè tirẹ̀, wọn a sì máa pe àwọn arabinrin wọn wá sí ilé láti bá wọn jẹ àsè. 5Nígbà tí wọ́n bá se àsè náà kárí tán, Jobu yóo ranṣẹ sí wọn láti rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún wọn. Ní àárọ̀ kutukutu, yóo dìde yóo rú ẹbọ sísun fún olukuluku wọn, yóo wí pé, “Bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti bú Ọlọrun ninu ọkàn wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni Jobu máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà.
6Ní ọjọ́ kan, àwọn ọmọ Ọlọrun wá láti fi ara wọn hàn níwájú OLUWA. Satani náà wà láàrin wọn. #Jẹn 6:2 7OLUWA bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”
Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.”
8OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?”
9Satani dáhùn pé, “Ṣé lásán ni Jobu bẹ̀rù ìwọ Ọlọrun ni? 10Ṣebí nígbà gbogbo ni ò ń dáàbò bo òun ati àwọn ará ilé rẹ̀, ati gbogbo ohun tí ó ní. Ò ń bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, o sì sọ ohun ìní rẹ̀ di pupọ. 11Ǹjẹ́, ìwọ mú gbogbo nǹkan wọnyi kúrò wò, o óo rí i pé yóo sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.” #Ifi 12:10
12OLUWA dá Satani lóhùn pé, “Ó dára, ohun gbogbo tí ó ní wà ní ìkáwọ́ rẹ. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òun fúnra rẹ̀.” Satani bá kúrò níwájú OLUWA.
Ọrọ̀ ati Àwọn Ọmọ Jobu Parun
13Ní ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Jobu ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkunrin, tí ó jẹ́ àgbà patapata, 14iranṣẹ kan wá sọ́dọ̀ Jobu, ó ròyìn fún un pé, “Àwọn akọ mààlúù ń fi àjàgà wọn kọlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko nítòsí wọn; 15àwọn ará Sabea rí wọn, wọ́n sì kó gbogbo wọn, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”
16Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Iná Ọlọrun wá láti ọ̀run, ó jó àwọn aguntan ati gbogbo darandaran patapata, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”
17Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ tí iranṣẹ mìíràn fi tún dé, ó ní, “Àwọn ẹgbẹ́ ogun Kalidea mẹta kọlù wá, wọ́n kó gbogbo ràkúnmí wa lọ, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”
18Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Bí àwọn ọmọ rẹ tí ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà, 19ìjì líle kan fẹ́ la àṣálẹ̀ kọjá, ó fẹ́ lu ilé náà, ó wó, ó sì pa gbogbo wọn, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”
20Jobu bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn; ó fá orí rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì sin OLUWA. 21Ó ní, “Ìhòòhò ni wọ́n bí mi, ìhòòhò ni n óo sì pada lọ. OLUWA níí fún ni ní nǹkan, OLUWA náà ní í sì í gbà á pada, ìyìn ni fún orúkọ OLUWA.” #Sir 40:1; 11:14
22Ninu gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀, kò sì dá Ọlọrun lẹ́bi.

Currently Selected:

JOBU 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy