Jobu bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn; ó fá orí rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì sin OLUWA. Ó ní, “Ìhòòhò ni wọ́n bí mi, ìhòòhò ni n óo sì pada lọ. OLUWA níí fún ni ní nǹkan, OLUWA náà ní í sì í gbà á pada, ìyìn ni fún orúkọ OLUWA.”
Ninu gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀, kò sì dá Ọlọrun lẹ́bi.