YouVersion Logo
Search Icon

SAKARAYA 4

4
Ìran nípa Ọ̀pá Fìtílà
1Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ tún pada wá, ó jí mi bí ẹni pé mo sùn. 2Ó bi mí pé kí ni mo rí.
Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje. 3Igi olifi meji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwo náà, ọ̀kan ní apá òsì.”#Ifi 11:4 4Nígbà náà ni mo bi angẹli náà pé, “OLUWA mi, Kí ni ìtumọ̀ àwọn kinní wọnyi?”
5Ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ìtumọ̀ wọn ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.”
Ìlérí Ọlọrun fún Serubabeli
6Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi.#Ẹsr 5:2 7Kí ni òkè ńlá jámọ́ níwájú Serubabeli? Yóo di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Serubabeli, O óo kọ́ ilé náà parí, bí o bá sì ti ń parí rẹ̀ ni àwọn eniyan yóo máa kígbe pé, “Áà! Èyí dára! Ó dára!” ’ ”
8OLUWA tún rán mi pé, 9“Serubabeli tí ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé Ọlọrun yìí ni yóo parí rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn eniyan mi yóo mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo rán ọ sí wọn. 10Inú àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí yóo dùn, wọn yóo sì rí okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubabeli. Àwọn fìtílà meje wọnyi ni ojú OLUWA tí ń wo gbogbo ayé.”#Ifi 5:6 11Mo bá bi í pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn igi olifi meji tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà?”#Ifi 11:4 12Mo tún bèèrè lẹẹkeji pé, “Kí ni ìtumọ̀ ẹ̀ka olifi meji, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrè wúrà meji, tí òróró olifi ń ṣàn jáde ninu wọn?”
13Ó tún bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ohun tí wọ́n jẹ́ ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.”
14Ó bá dáhùn, ó ní, “Àwọn wọnyi ni àwọn meji tí a ti fi òróró yàn láti jẹ́ òjíṣẹ́ OLUWA gbogbo ayé.”

Currently Selected:

SAKARAYA 4: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy