YouVersion Logo
Search Icon

SAKARAYA 2

2
Ìran nípa Okùn Ìwọ̀n
1Bí mo tún ti gbé ojú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́. 2Mo bi í pé, “Níbo ni ò ń lọ?” Ó bá dáhùn pé, “Mò ń lọ wọn Jerusalẹmu, kí n lè mọ òòró ati ìbú rẹ̀ ni.”
3Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bọ́ siwaju, angẹli mìíràn sì lọ pàdé rẹ̀, Angẹli àkọ́kọ́ sọ fún ekeji pé, 4“Sáré lọ sọ fún ọmọkunrin tí ó ní okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ pé, eniyan ati ẹran ọ̀sìn yóo pọ̀ ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè mọ odi yí i ká. 5Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ odi iná tí n óo yí i ká, tí n óo máa dáàbò bò ó, n óo sì fi ògo mi kún inú rẹ̀.”
Pípe Àwọn tí A kó lẹ́rú pada Wálé
6OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ àríwá. Lóòótọ́ èmi ni mo fọn yín ká bí afẹ́fẹ́ sí igun mẹrẹẹrin ayé, 7ṣugbọn nisinsinyii, ẹ sá àsálà lọ sí Sioni, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Babiloni. 8Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán ni sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ko yín lẹ́rú, nítorí ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín, fọwọ́ kan ẹyinjú èmi OLUWA.” 9N óo bá àwọn ọ̀tá yín jà; wọn yóo sì di ẹrú àwọn tí ń sìn wọ́n.
Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA àwọn ọmọ ogun.
10OLUWA ní, “Ẹ kọrin ayọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín máa dùn, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, nítorí pé mò ń bọ̀ wá máa ba yín gbé. 11Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo parapọ̀ láti di eniyan mi nígbà náà. N óo máa gbé ààrin yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ranṣẹ si yín. 12N óo jogún Juda bí ohun ìní mi ninu ilẹ̀ mímọ́, n óo sì yan Jerusalẹmu.”
13Ẹ̀yin eniyan, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA, nítorí ó ń jáde bọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀.

Currently Selected:

SAKARAYA 2: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy