YouVersion Logo
Search Icon

RUTU 2

2
Rutu Ṣiṣẹ́ ninu Oko Boasi
1Ní àkókò yìí, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà ninu ìdílé Elimeleki, ẹbí kan náà ni ọkunrin yìí ati ọkọ Naomi. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi. 2Ní ọjọ́ kan, Rutu sọ fún Naomi, ó ní, “Jẹ́ kí n lọ sí oko ẹnìkan, tí OLUWA bá jẹ́ kí n bá ojurere rẹ̀ pàdé, n ó máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọ́n ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀.” Naomi bá dá a lóhùn, ó ní, “Ó dára, máa lọ, ọmọ mi.”#Lef 19:9-10; Diut 24:19
3Rutu bá gbéra, ó lọ sí oko ọkà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà gbàgbé sílẹ̀. Oko tí ó lọ jẹ́ ti Boasi, ìbátan Elimeleki.
4Kò pẹ́ pupọ ni Boasi náà dé láti Bẹtilẹhẹmu. Ó kí àwọn tí wọn ń kórè ọkà, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín.” Àwọn náà dáhùn pé, “Kí OLUWA bukun ọ.”
5Boasi bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ́ alákòóso àwọn tí ń kórè, ó ní, “Ọmọ ta ni ọmọbinrin yìí?”
6Iranṣẹ rẹ̀ náà bá dá a lóhùn, ó ní, “Obinrin ará Moabu, tí ó bá Naomi pada láti ilẹ̀ Moabu ni. 7Ó bẹ̀ wá pé kí á jọ̀wọ́ kí á fún òun ní ààyè láti máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀. Láti àárọ̀ tí ó ti dé, ni ó ti ń ṣiṣẹ́ títí di àkókò yìí láìsinmi, bí ó ti wù kí ó mọ.”
8Boasi bá pe Rutu, ó ní, “Gbọ́, ọmọ mi, má lọ sí oko ẹlòmíràn láti ṣa ọkà, má kúrò ní oko yìí, ṣugbọn faramọ́ àwọn ọmọbinrin mi. 9Oko tí wọn ń kórè rẹ̀ yìí ni kí o kọjú sí, kí o sì máa tẹ̀lé wọn. Mo ti kìlọ̀ fún àwọn ọdọmọkunrin wọnyi pé wọn kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Nígbà tí òùgnbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ sí ìdí àmù, kí o sì mu ninu omi tí àwọn ọdọmọkunrin wọnyi bá pọn.”
10Rutu bá wólẹ̀ ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Mo dúpẹ́ pé mo rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ tó báyìí, o sì ṣe akiyesi mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni mí.”
11Ṣugbọn Boasi dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ìyá ọkọ rẹ, láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú ni wọ́n ti sọ fún mi patapata, ati bí o ti fi baba ati ìyá rẹ sílẹ̀, tí o kúrò ní ìlú yín, tí o wá sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan tí o kò mọ̀ rí. 12OLUWA yóo san ẹ̀san gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ọ. Abẹ́ ìyẹ́ apá OLUWA Ọlọrun Israẹli ni o wá, fún ààbò, yóo sì fún ọ ní èrè kíkún.” 13Rutu bá dáhùn, ó ní, “O ṣàánú mi gan-an ni, oluwa mi, nítorí pé o ti tù mí ninu, o sì ti fi sùúrù bá èmi iranṣẹbinrin rẹ sọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin rẹ.”
14Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Boasi pe Rutu, ó ní, “Wá jẹun, kí o fi òkèlè rẹ bọ inú ọtí kíkan.” Rutu bá jókòó lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń kórè ọkà, Boasi gbé ọkà yíyan nawọ́ sí i; ó sì jẹ àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù. 15Nígbà tí Rutu dìde, láti tún máa ṣa ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí ó máa ṣa ọkà láàrin àwọn ìtí ọkà tí ẹ dì jọ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. 16Kí ẹ tilẹ̀ fa ọkà yọ fún un ninu ìtí, kí ẹ sì tún fi í sílẹ̀ láti ṣa ọkà, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu.”
17Rutu bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó pa ọkà tí ó ṣà, ohun tí ó rí tó ìwọ̀n efa ọkà baali kan. 18Ó gbé e, ó sì lọ sílé. Ó fi ọkà tí ó rí han ìyá ọkọ rẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ tí ó jẹ kù. 19Ìyá ọkọ rẹ̀ bi í léèrè, ó ní, “Níbo ni o ti ṣa ọkà lónìí, níbo ni o sì ti ṣiṣẹ́? OLUWA yóo bukun ẹni tí ó ṣàkíyèsí rẹ.”
Rutu bá sọ inú oko ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní, “Inú oko ọkunrin kan tí wọ́n ń pè ní Boasi ni mo ti ṣa ọkà lónìí.”
20Naomi dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA tí kì í gbàgbé láti ṣàánú ati òkú ọ̀run, ati alààyè bukun Boasi.” Naomi bá ṣe àlàyé fún Rutu pé, ẹbí àwọn ni Boasi, ati pé ọ̀kan ninu àwọn tí ó súnmọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí ni.#Lef 25:25.
21Rutu tún fi kún un fún Naomi pé, “Boasi tilẹ̀ tún wí fún mi pé, n kò gbọdọ̀ jìnnà sí àwọn iranṣẹ òun títí tí wọn yóo fi parí ìkórè ọkà Baali rẹ̀.”
22Naomi dáhùn, ó ní, “Ó dára, máa bá àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ, ọmọ mi, kí wọ́n má baà yọ ọ́ lẹ́nu bí o bá lọ sinu oko ọkà ẹlòmíràn.” 23Rutu bá ń bá àwọn ọmọbinrin Boasi lọ láti ṣa ọkà títí wọ́n fi parí ìkórè ọkà Baali, ó sì ń gbé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀.

Currently Selected:

RUTU 2: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy