YouVersion Logo
Search Icon

ROMU 16

16
Paulu Kí Ọpọlọpọ Eniyan ninu Ìjọ Romu
1Mo fẹ́ kí ẹ gba Febe bí arabinrin wa, ẹni tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkiria. 2Ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ní orúkọ Kristi gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ onigbagbọ. Kí ẹ ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nàkọ́nà tí ó bá fẹ́; nítorí ó jẹ́ ẹni tí ó ran ọpọlọpọ eniyan ati èmi pàápàá lọ́wọ́.
3Ẹ kí Pirisila ati Akuila, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi Jesu.#A. Apo 18:2 4Wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti gbà mí lọ́wọ́ ikú. Èmi nìkan kọ́ ni mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu náà dúpẹ́ pẹlu. 5Ẹ kí ìjọ tí ó wà ní ilé wọn náà.
Ẹ kí Epenetu àyànfẹ́ mi, ẹni tí ó jẹ́ onigbagbọ kinni ní ilẹ̀ Esia. 6Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ láàrin yín. 7Ẹ kí Andironiku ati Junia, àwọn ìbátan mi tí a jọ wà lẹ́wọ̀n. Olókìkí ni wọ́n láàrin àwọn òjíṣẹ́ Kristi, wọ́n sì ti di onigbagbọ ṣiwaju mi.
8Ẹ kí Ampiliatu àyànfẹ́ mi ninu Oluwa. 9Ẹ kí Ubanu alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi ati Sitaku àyànfẹ́ mi. 10Ẹ kí Apele, akikanju onigbagbọ. Ẹ kí àwọn ará ilé Arisitobulu. 11Ẹ kí Hẹrodioni ìbátan mi. Ẹ kí àwọn ará ilé Nakisu tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ.
12Ẹ kí Tirufina ati Tirufosa, àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ Oluwa. Ẹ kí Pasisi, arabinrin àyànfẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ ninu Oluwa. 13Ẹ kí Rufọsi, àṣàyàn onigbagbọ ati ìyá rẹ̀ tí ó tún jẹ́ ìyá tèmi náà. 14Ẹ kí Asinkiritu, Filegọnta, Herime, Patiroba, Herima ati àwọn arakunrin tí ó wá pẹlu wọn. 15Ẹ kí Filologu ati Julia, Nerea ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa ati gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà lọ́dọ̀ wọn.
16Ẹ rọ̀ mọ́ ara yín, kí ẹ sì kí ara yín pẹlu alaafia. Gbogbo ìjọ Kristi kí yín.#Mak 15:21
Paulu Ṣe Ìkìlọ̀
17Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín pé kí ẹ máa fura sí àwọn tí ó ń dá ìyapa sílẹ̀ ati àwọn tí ń múni ṣìnà, tí wọn ń ṣe àwọn nǹkan tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ yẹra fún irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀. 18Nítorí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kì í ṣe iranṣẹ Oluwa wa Kristi, ikùn ara wọn ni wọ́n ń bọ. Wọn a máa fi ọ̀rọ̀ dídùn ati kí á máa pọ́n eniyan tan àwọn tí kò bá fura jẹ. 19Ìròyìn ti tàn ká ibi gbogbo pé ẹ dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Èyí mú inú mi dùn nítorí yín. Mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ amòye ninu nǹkan rere, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ òpè ní ti àwọn nǹkan burúkú. 20Kí Ọlọrun orísun alaafia mu yín ṣẹgun Satani ní kíákíá. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín.
Àwọn Tí Ó Wà lọ́dọ̀ Paulu Kí Ìjọ Romu
21Timoti alábàáṣiṣẹ́ mi ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Lukiusi ati Jasoni ati Sosipata, àwọn ìbátan wa.#A. Apo 16:1
22Èmi Tatiu tí mò ń bá Paulu kọ ìwé yìí ki yín: Ẹ kú iṣẹ́ Oluwa.
23Gaiyu náà ki yín. Òun ni ó gbà mí lálejò bí ó ti gba gbogbo ìjọ lálejò. Erastu, akápò ìlú, ki yín. Kuatu arakunrin wa náà ki yín.
[ 24Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin.]#a A. Apo 19:29; 1:14; b 2 Tim 4:20
Oore-ọ̀fẹ́
25Ògo ni fún ẹni tí ó lágbára láti mu yín dúró gbọningbọnin, gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ati iwaasu nípa Jesu Kristi ti wí ati gẹ́gẹ́ bí àdììtú tí Ọlọrun dì láti ayérayé, ṣugbọn tí ó wá tú 26ní àkókò yìí. Ìwé àwọn wolii ni ó ṣe ìṣípayá ohun tí ó fara pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọrun ayérayé, pé kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́, kí wọ́n mọ̀, kí wọ́n sì gbà.
27Ògo ni fún Ọlọrun ọlọ́gbọ́n kanṣoṣo nípa Jesu Kristi títí laelae. Amin.#16:27 Àwọn Bibeli àtijọ́ kan fi àwọn ẹsẹ yìí 16:25-27 tẹ̀lé 14:23. Bibeli àtijọ́ kan fi í tẹ̀lé 15:33. Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn kò ní àwọn ẹsẹ yìí rárá.

Currently Selected:

ROMU 16: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy