YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 122

122
Ìyìn Jerusalẹmu
1Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,
“Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé OLUWA.”
2A ti tẹsẹ̀ bọ inú ìgboro rẹ, Jerusalẹmu.
3Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí a kọ́,
tí gbogbo rẹ̀ já pọ̀ di ọ̀kan.
4Níbi tí àwọn ẹ̀yà,
àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ,
láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA
gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli.
5Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí,
àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi.
6Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu!
“Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ!
7Kí alaafia ó wà ninu rẹ,
kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.”
8Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi,
n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.”
9Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa,
èmi óo máa wá ire rẹ.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 122: YCE

Highlight

Copy

Compare

Share

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in