YouVersion Logo
Search Icon

ÌWÉ ÒWE Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Òwe jẹ́ àkọsílẹ̀ àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ìwà ati ẹ̀sìn tí a ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ lówe lówe. Ọ̀pọ̀ ninu àwọn òwe wọnyi jẹ mọ́ ìhùwàsí ati ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojumọ. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìránnilétí pé, “Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpìlẹ̀ ọgbọ́n.” Lẹ́yìn náà ó mẹ́nuba oríṣìíríṣìí ìhùwàsí tí ó tọ̀nà nípa ti ẹ̀sìn ati ti ọgbọ́n ati ti ìwà ọmọlúwàbí. Ọpọlọpọ àwọn ọ̀rọ̀ ṣókíṣókí inú ìwé yìí fi àròjinlẹ̀ àwọn olùkọ́ ní ilẹ̀ Israẹli ní ayé àtijọ́ hàn, nípa ohun tí ó tọ́ kí ọlọ́gbọ́n eniyan ṣe tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tabi òmíràn bá ṣẹlẹ̀. Díẹ̀ ninu àwọn òwe wọnyi níí ṣe pẹlu àjọṣepọ̀ láàrin ẹbí, àwọn mìíràn níí ṣe pẹlu òwò ṣíṣe. Díẹ̀ níí ṣe pẹlu ìhùwàsí ní àwùjọ, àwọn mìíràn níí ṣe pẹlu ẹ̀mí ìkóra-ẹni-níjàánu. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ mọ́ iyì tí ó wà ninu ìwà ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù, ẹ̀mí ọ̀wọ̀ fún àwọn talaka, ati ìṣòtítọ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ ẹni.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Orin ìyìn nípa ìwà ọgbọ́n 1:1–9:18
Àwọn òwe Solomoni 10:1–29:27
Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri 30:1-33
Oniruuru ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ 31:1-31

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy