YouVersion Logo
Search Icon

ÌWÉ ÒWE 3

3
Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́
1Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ,
sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ,
2nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn
ati ọpọlọpọ alaafia.
3Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀,
so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ,
kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.
4Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì #Luk 2:25
lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan.
5Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,
má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ.
6Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ,
yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́.
7Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, #Rom 12:16
bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi.
8Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ,
ati ìtura fún egungun rẹ.
9Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWA
pẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ.
10Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú,
ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya.
11Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìtọ́ni OLUWA, #Job 5:17
má sì ṣe jẹ́ kí ìbáwí rẹ̀ sú ọ.
12Nítorí ẹni tí OLUWA bá fẹ́ níí báwí #Heb 12: 5-6, Ifi 3:19
gẹ́gẹ́ bí baba tí máa ń bá ọmọ rẹ̀ tí ó bá fẹ́ràn wí.
13Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí,
ati ẹni tí ó ní òye.
14Nítorí èrè rẹ̀ dára
ju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ.
15Ọgbọ́n níye lórí
ó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,
kò sí ohun tí o lè fi wé e,
ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́.
16Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,
ọrọ̀ ati iyì sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.
17Ọ̀nà rẹ̀ tura pupọ,
alaafia sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀.
18Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn,
ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin.
19Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀,
òye ni ó sì fi dá ọ̀run.
20Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde,
tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu.
21Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú,
má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,
22wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ,
ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
23Nígbà náà ni o óo máa rìn
láìléwu ati láìkọsẹ̀.
24Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́,
bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ.
25Má bẹ̀rù àjálù òjijì,
tabi ìparun àwọn ẹni ibi,
nígbà tí ó bá dé bá ọ,
26nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ,
kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté.
27Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, #Sir 4:3
nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é.
28Má sọ fún aládùúgbò rẹ pé,
“Máa lọ ná, n óo fún ọ tí o bá pada wá lọ́la,”
nígbà tí ohun tí ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ.
29Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹ
tí ń fi inú kan bá ọ gbé.
30Má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà láìnídìí,
nígbà tí kò ṣe ọ́ níbi.
31Má ṣe ìlara ẹni ibi
má sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀.
32Nítorí OLUWA kórìíra alárèékérekè,
ṣugbọn ó ní igbẹkẹle ninu àwọn tí wọn dúró ṣinṣin.
33Ègún OLUWA wà lórí ìdílé ẹni ibi,
ṣugbọn a máa bukun ibùgbé àwọn olódodo.
34A máa fi àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn ṣe ẹlẹ́yà, #Jak 4:6, 1 Pet 5:5
ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.
35Ọlọ́gbọ́n yóo jogún iyì,
ṣugbọn ojú yóo ti òmùgọ̀.

Currently Selected:

ÌWÉ ÒWE 3: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy