MATIU 5:2-11
MATIU 5:2-11 YCE
Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé: “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú, nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́, nítorí wọn yóo rí Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan, nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. “Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi.