YouVersion Logo
Search Icon

MATIU 14

14
Ikú Johanu Onítẹ̀bọmi
(Mak 6:14-29; Luk 9:7-9)
1Ní àkókò náà, Hẹrọdu ọba gbúròó Jesu. 2Ó wí fún àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni èyí. Òun ni ó jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ó fi ní agbára láti lè ṣe iṣẹ́ ìyanu.”
3Nítorí Hẹrọdu yìí ni ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú Johanu, kí wọ́n dè é, kí wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin Hẹrọdu. 4Nítorí Johanu sọ fún Hẹrọdu pé kò tọ́ fún un láti fi Hẹrọdiasi ṣaya.#Luk 3:19-20 #Lef 18:16; 20:21 5Hẹrọdu fẹ́ pa á, ṣugbọn ó bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí wọ́n gbà pé wolii ni Johanu.
6Nígbà tí Hẹrọdu ń ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀, ọdọmọbinrin Hẹrọdiasi bẹ̀rẹ̀ sí jó lójú agbo. Èyí dùn mọ́ Hẹrọdu ninu 7tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkohun tí ó bá bèèrè.
8Lẹ́yìn tí ìyá ọmọbinrin yìí ti kọ́ ọ ní ohun tí yóo bèèrè, ó ní, “Gbé orí Johanu Onítẹ̀bọmi wá fún mi nisinsinyii ninu àwo pẹrẹsẹ kan.”
9Ó dun ọba, ṣugbọn nítorí pé ó ti búra, ati nítorí àwọn tí ó wà níbi àsè, ó gbà láti fi fún un. 10Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ Johanu lórí ninu ẹ̀wọ̀n tí ó wá. 11Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá ninu àwo pẹrẹsẹ, wọ́n gbé e fún ọdọmọbinrin náà. Ó bá lọ gbé e fún ìyá rẹ̀. 12Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu bá wá, wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ, wọ́n sin ín; wọ́n sì lọ ròyìn fún Jesu.
Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan
(Mak 6:30-44; Luk 9:10-17; Joh 6:1-14)
13Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkan tí eniyan kò sí, kí ó lè dá wà. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, wọ́n gba ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ láti ìlú wọn, wọ́n tẹ̀lé e. 14Bí ó ti ń gúnlẹ̀, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan. Àánú wọn ṣe é, ó bá wo àwọn tí wọ́n ṣàìsàn ninu wọn sàn.
15Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ní, “Aṣálẹ̀ ni ibí yìí, ọjọ́ sì ti lọ. Fi àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ ra oúnjẹ fún ara wọn ninu àwọn ìletò.”
16Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò yẹ kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní oúnjẹ jẹ.”
17Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí oúnjẹ níhìn-ín, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji.”
18Ó ní, “Ẹ kó wọn wá fún mi níhìn-ín.” 19Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan jókòó lórí koríko. Ó mú burẹdi marun-un náà ati ẹja meji; ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́, ó bá bù wọ́n, ó kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá pín in fún àwọn eniyan. 20Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, àjẹkù sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila. 21Àwọn eniyan tí ó jẹun tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.
Jesu Rìn lórí Omi
(Mak 6:45-52; Joh 6:15-21)
22Lẹsẹkẹsẹ, ó bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn wọ ọkọ̀ ojú omi ṣáájú òun lọ sí òdìkejì, nígbà tí ó ń tú àwọn eniyan ká. 23Nígbà tí ó tú wọn ká tán, ó gun orí òkè lọ gbadura, òun nìkan. Nígbà tí alẹ́ lẹ́, òun nìkan ni ó wà níbẹ̀. 24Ọkọ̀ ti kúrò ní èbúté, ó ti bọ́ sí agbami. Ìgbì omi wá ń dààmú ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn.
25Nígbà tí ó di nǹkan bí agogo mẹta òru, Jesu ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó ń rìn lójú omi òkun. 26Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé, “Iwin ni!” Wọ́n bá kígbe, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n.
27Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!”
28Peteru sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni, sọ pé kí n máa rìn bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ lójú omi.”
29Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu. 30Ṣugbọn nígbà tí ó rí i tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́, ẹ̀rù bà á, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rì. Ó bá kígbe pé, “Oluwa, gbà mí!”
31Lẹsẹkẹsẹ Jesu bá fà á lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ìwọ onigbagbọ kékeré yìí! Kí ni ó mú ọ ṣe iyè meji?”
32Bí wọ́n ti wọ inú ọkọ́ ni afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. 33Àwọn tí ó wà ninu ọkọ̀ júbà rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Lóòótọ́, Ọmọ Ọlọrun ni ọ́!”
Jesu Wo Àwọn Aláìsàn Sàn ní Genesarẹti
(Mak 6:53-56)
34Lẹ́yìn tí wọ́n ti gúnlẹ̀, wọ́n dé ilẹ̀ Genesarẹti. 35Àwọn eniyan ibẹ̀ ti dá a mọ̀, wọ́n bá ranṣẹ lọ sí gbogbo agbègbè ibẹ̀; wọ́n gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 36Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn sá lè fi ọwọ́ kan etí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án ni ó mú lára dá.

Currently Selected:

MATIU 14: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy