ẸKÚN JEREMAYA 3:22-27
ẸKÚN JEREMAYA 3:22-27 YCE
Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun, àánú rẹ̀ kò sì lópin; ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi, nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.” OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é, tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀. Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA. Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe.