YouVersion Logo
Search Icon

JOṢUA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Joṣua ni ó sọ ìtàn bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe jagun gba ilẹ̀ Kenaani, lábẹ́ àkóso Joṣua, ẹni tí ó gba ipò Mose gẹ́gẹ́ bí olùdarí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pataki tí a sọ nípa rẹ̀ ninu ìwé yìí ni: bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe rékọjá odò Jọdani; bí odi Jẹriko ṣe wó lulẹ̀; ogun tí wọ́n jà ní Ai, ati bí wọ́n ṣe tún majẹmu dá pẹlu Ọlọrun. Ẹsẹ tí ọpọlọpọ eniyan mọ̀ jù ninu ìwé yìí ni orí 24 ẹsẹ 15 tí ó kà báyìí pé, “Ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí... Ní tèmi, ati àwọn ará ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.”
Àwọn Ohun tí ó wà ninú Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ṣiṣẹgun àwọn ará Kenaani 1:1–12:24
Pínpín ilẹ̀ náà 13:1–21:45
a. Ilẹ̀ apá ìlà oòrùn Jọdani 13:1-33
b. Ilẹ̀ apá ìwọ̀ oòrùn Jọdani 14:1–19:51
d. Àwọn ìlú ààbò 20:1-9
e. Àwọn ìlú àwọn ọmọ Lefi 21:1-45
Àwọn ẹ̀yà ìlà oòrùn pada sí agbègbè wọn 22:1-34
Ọ̀rọ̀ ìdágbére Joṣua 23:1-16
Àtúnṣe majẹmu ní Ṣekemu 24:1-33

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy