YouVersion Logo
Search Icon

JOṢUA 2

2
Joṣua Rán Àwọn Amí Lọ sí Jẹriko
1Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu. 2Àwọn kan bá lọ sọ fún ọba Jẹriko pé, “Àwọn ọkunrin kan, lára àwọn ọmọ Israẹli, wá sí ibí ní alẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ yìí.” 3Ọba Jẹriko bá ranṣẹ sí Rahabu ó ní, “Kó àwọn ọkunrin tí wọn dé sọ́dọ̀ rẹ jáde wá, nítorí pé wọ́n wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni.”#Heb 11:31; Jak 2:25.
4Ṣugbọn obinrin náà ti kó àwọn ọkunrin mejeeji pamọ́, ó dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni àwọn ọkunrin meji kan wá sọ́dọ̀ mi, ṣugbọn n kò mọ ibi tí wọn ti wá. 5Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè ni wọ́n jáde lọ, n kò sì mọ ibi tí wọ́n lọ. Ẹ tètè máa lépa wọn lọ, ẹ óo bá wọn lọ́nà.” 6Ṣugbọn ó ti kó wọn gun orí òrùlé rẹ̀, ó sì ti fi wọ́n pamọ́ sáàrin pòpórò igi ọ̀gbọ̀ tí ó tò jọ sibẹ. 7Àwọn tí ọba rán bá bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọkunrin náà lọ ní ọ̀nà odò Jọdani, títí dé ibi tí ọ̀nà ti rékọjá odò náà, bí àwọn tí ọba rán ti jáde ní ìlú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi ìlú náà.
8Kí àwọn amí meji náà tó sùn, Rahabu gun òrùlé lọ bá wọn, ó ní, 9“Mo mọ̀ pé OLUWA ti fi ilẹ̀ yìí lé e yín lọ́wọ́, jìnnìjìnnì yín ti bò wá, ẹ̀rù yín sì ti ń ba gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí. 10Nítorí a ti gbọ́ bí OLUWA ti mú kí Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ jáde ní Ijipti, a sì ti gbọ́ ohun tí ẹ ṣe sí Sihoni ati Ogu, àwọn ọba ará Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani, bí ẹ ṣe pa wọ́n run patapata.#a Eks 14:21; b Nọm 21:21-35 11Bí a ti gbọ́ ni jìnnìjìnnì ti bò wá, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì ti bá gbogbo eniyan nítorí yín, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun ọ̀run ati ayé. 12Nítorí náà, ẹ fi OLUWA búra fún mi nisinsinyii pé, bí mo ti ṣe yín lóore yìí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ṣe ilé baba mi lóore, kí ẹ sì fún mi ní àmì tí ó dájú. 13Kí ẹ dá baba mi ati ìyá mi sí, ati àwọn arakunrin mi, ati àwọn arabinrin mi, ati gbogbo àwọn eniyan wọn; ẹ má jẹ́ kí á kú.”
14Àwọn ọkunrin náà bá dá a lóhùn pé, “Kí OLUWA gba ẹ̀mí wa bí a bá pa yín. Bí o kò bá ṣá ti sọ ohun tí a wá ṣe níhìn-ín fún ẹnikẹ́ni, a óo ṣe ọ́ dáradára, a óo sì jẹ́ olóòótọ́ sí ọ nígbà tí OLUWA bá fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́.”
15Ó bá fi okùn kan sọ̀ wọ́n kalẹ̀ láti ojú fèrèsé, nítorí pé àkọ́pọ̀ mọ́ odi ìlú ni wọ́n kọ́ ilé rẹ̀, inú odi yìí ni ó sì ń gbé. 16Ó bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ sá lọ sí orí òkè, kí àwọn tí wọ́n ń lépa yín má baà pàdé yín lójú ọ̀nà. Ẹ sá pamọ́ fún ọjọ́ mẹta, títí tí wọn óo fi pada dé. Lẹ́yìn náà, ẹ máa bá tiyín lọ.”
17Àwọn ọkunrin náà sọ fún Rahabu pé, “A óo mú ìlérí tí o mú kí á fi ìbúra ṣe fún ọ ṣẹ. 18Nígbà tí a bá wọ ilẹ̀ yìí, mú okùn pupa yìí, kí o so ó mọ́ ibi fèrèsé tí o ti sọ̀ wá kalẹ̀. Kó baba, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ, ati gbogbo àwọn ará ilé baba rẹ sí inú ilé rẹ. 19Bí ẹnikẹ́ni bá jáde kúrò ninu ilé rẹ lọ sí ààrin ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀, kò sì ní sí ẹ̀bi lọ́rùn wa. Ṣugbọn bí wọn bá pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí wa. 20Ṣugbọn bí o bá sọ ohun tí a wá ṣe fún ẹnikẹ́ni, ẹ̀bi ìlérí tí a fi ìbúra ṣe yìí kò ní sí lórí wa mọ́.” 21Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ ti wí gan-an, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí.” Ó ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì lọ; ó bá so okùn pupa náà mọ́ fèrèsé rẹ̀.
22Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sá lọ sí orí òkè, wọ́n sì farapamọ́ fún ọjọ́ mẹta, títí tí àwọn tí wọn ń lépa wọn fi pada; nítorí pé wọ́n ti wá wọn káàkiri títí ní gbogbo ojú ọ̀nà, wọn kò sì rí wọn. 23Àwọn ọkunrin meji náà sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ́n lọ bá Joṣua, ọmọ Nuni, wọ́n bá sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un. 24Wọ́n sọ fún Joṣua pé, “Láìṣe àní àní, OLUWA ti fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́, ìdààmú ọkàn sì ti bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà nítorí wa.”

Currently Selected:

JOṢUA 2: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy