YouVersion Logo
Search Icon

JONA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Jona yàtọ̀ sí àwọn ìwé wolii yòókù. Ìwé yìí sọ ìtàn ohun tí ojú wolii kan, tí ń sá fún àṣẹ Ọlọrun rí. Ọlọrun rán an lọ sí ìlú Ninefe, olú-ìlú ilẹ̀ Asiria, tí àwọn ará ibẹ̀ jẹ́ ọ̀tá aṣekúpani fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn lọ́kàn Jona ó gbàgbọ́ pé Ọlọrun kò ní pa ìlú náà run bí ó ti ń lérí. Nítorí náà, Jona kò fẹ́ lọ sí Ninefe. Lẹ́yìn ọpọlọpọ nǹkan tí ojú rẹ̀ rí, ó lọ jíṣẹ́ tí Ọlọrun rán an. Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kò ṣẹ, ó takété sí àwọn eniyan yòókù.
Ìwé yìí fi ìfẹ́ Ọlọrun sí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ hàn ketekete. Ní pataki jùlọ, ó fi Ọlọrun hàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ati pé ó tẹ́ ẹ lọ́rùn kí ó dáríjì ọ̀tá àwọn eniyan rẹ̀ kí ó sì gbà wọ́n là, ju pé kí ó fìyà jẹ wọ́n, kí ó sì pa wọ́n run lọ.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìpè Jona ati bí ó ti kọ̀ láti jẹ́ ìpè náà 1:1-17
Jona ronupiwada ó sì rí ìgbàlà 2:1-10
Iṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun fún àwọn ará Ninefe 3:1-10
Àánú Ọlọrun lórí Ninefe 4:1-11

Currently Selected:

JONA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy