YouVersion Logo
Search Icon

ÀWỌN ADÁJỌ́ 2

2
Angẹli OLUWA ní Bokimu
1Angẹli OLUWA gbéra láti Giligali, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní Bokimu, ó sọ fún wọn pé, “Mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá yín pé n óo fún wọn. Mo ní, ‘N kò ní yẹ majẹmu tí mo bá yín dá, 2ati pé, ẹ kò gbọdọ̀ bá èyíkéyìí ninu àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí dá majẹmu kankan, ẹ sì gbọdọ̀ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀.’ Ṣugbọn ẹ kò mú àṣẹ tí mo pa fun yín ṣẹ. Irú kí ni ẹ dánwò yìí? 3Nítorí náà, n kò ní lé wọn jáde fun yín mọ́; ṣugbọn wọn yóo di ọ̀tá yín, àwọn oriṣa wọn yóo sì di tàkúté fún yín.” 4Nígbà tí Angẹli OLUWA sọ ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. 5Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu, wọ́n sì rúbọ sí OLUWA níbẹ̀.#Eks 34:12-13; Diut 7:2-5
Ikú Joṣua
6Nígbà tí Joṣua tú àwọn ọmọ Israẹli ká, olukuluku wọn pada lọ sí orí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. 7Àwọn eniyan náà sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n kù lẹ́yìn rẹ̀ wà láàyè, àwọn tí wọ́n fi ojú rí àwọn iṣẹ́ ńlá tí OLUWA ṣe fún Israẹli. 8Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA, ṣaláìsí nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. 9Wọ́n sì sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní ìhà àríwá òkè Gaaṣi. 10Gbogbo ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọ́n mọ OLUWA ati ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli patapata ni wọ́n kú, àwọn ìran mìíràn sì dìde lẹ́yìn wọn, wọn kò mọ OLUWA, ati gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli.#Joṣ 19:49-50.
Israẹli Kọ̀ láti Sin OLUWA
11Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ oriṣa Baali. 12Wọ́n kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn tí ó kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n ń bọ lára àwọn oriṣa àwọn tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n sì mú inú bí OLUWA. 13Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n ń bọ oriṣa Baali ati Aṣitarotu. 14Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́. 15Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá jáde lọ láti jagun, OLUWA á kẹ̀yìn sí wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti kìlọ̀ fún wọn tí ó sì búra fún wọn, ìdààmú a sì dé bá wọn.
16Lẹ́yìn náà, OLUWA á gbé àwọn adájọ́ kan dìde, àwọn adájọ́ náà á sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà tí ń kó wọn ní nǹkan. 17Sibẹsibẹ, wọn kì í gbọ́ ti àwọn aṣiwaju wọn. Wọn a máa sá lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa káàkiri, wọn a sì máa bọ wọ́n. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n á yipada kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba wọn ń rìn. Àwọn baba wọn a máa pa òfin OLUWA mọ́, ṣugbọn ní tiwọn àwọn kì í pa á mọ́. 18Nígbàkúùgbà tí OLUWA bá gbé aṣiwaju kan dìde fún wọn, OLUWA a máa wà pẹlu aṣiwaju náà, a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, ní àkókò aṣiwaju náà. Ìkérora àwọn ọmọ Israẹli a máa mú kí àánú wọn ṣe OLUWA, nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì ń ni wọ́n lára. 19Ṣugbọn bí aṣiwaju yìí bá ti kú, kíá, wọn a tún ti yipada, wọn a sì tún ti máa ṣe ohun tí ó burú ju ohun tí àwọn baba wọn ti ṣe lọ. Wọn a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọ́n a máa bọ wọ́n, wọn a sì máa foríbalẹ̀ fún wọn. Wọn kì í sì í fi ìṣe wọn ati oríkunkun wọn sílẹ̀. 20Nítorí náà inú a bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, a sì wí pé, “Àwọn eniyan wọnyi ti da majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba wọn, wọn kò sì fetí sí òfin mi. 21Láti ìsinsìnyìí lọ n kò ní lé èyíkéyìí, ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù kí Joṣua tó kú, jáde fún wọn. 22Àwọn ni n óo lò láti wò ó bí àwọn ọmọ Israẹli yóo máa tọ ọ̀nà tí mo là sílẹ̀, bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe.” 23Nítorí náà, OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀ náà, kò tètè lé wọn jáde bí kò ti fún Joṣua lágbára láti ṣẹgun wọn.

Currently Selected:

ÀWỌN ADÁJỌ́ 2: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy