YouVersion Logo
Search Icon

HOSIA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Apá ìhà àríwá Israẹli ni wolii Hosia ti waasu, lẹ́yìn wolii Amosi, ní àkókò ìdààmú, kí Samaria tó ṣubú ní ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mọkanlelogun kí á tó bí OLUWA wa, (721 B.C.) Ìbọ̀rìṣà àwọn eniyan náà ati ainigbagbọ ninu Ọlọrun jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún Hosia. Ó lo ìtàn iyawo rẹ̀ Gomeri, alaiṣootọ, gẹ́gẹ́ bí àfiwé àwọn eniyan Ọlọrun tí wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀. Fún ìdí èyí, ìdájọ́ yóo wá sórí Israẹli; ṣugbọn sibẹ, ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí àwọn eniyan rẹ̀ yóo borí. Yóo pe àwọn eniyan náà pada yóo sì da ibukun rẹ̀ pada sí orí wọn. Ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ yìí hàn ninu àwọn gbolohun rẹ̀; Bí àpẹẹrẹ, “Mo ṣe lè fi ọ́ sílẹ̀, Israẹli? Mo ṣe lè pa ọ́ tì? ... Ọkàn mi kò lè gbà á! Ìfẹ́ tí mo ní sí ọ jinlẹ̀.” (11:8)
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Igbeyawo Hosia ati ìdílé rẹ̀ 1:1–3:5
Àwọn ìran ibi tí a rí sí Israẹli 4:1–13:6
Ìran nípa ìrònúpìwàdà ati ẹ̀jẹ́ 14:1–9

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy