YouVersion Logo
Search Icon

ISIKIẸLI 3

3
1Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ Eniyan, jẹ ohun tí a fún ọ; jẹ ìwé tí a ká yìí, kí o sì lọ bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”
2Mo bá la ẹnu, ó sì fún mi ní ìwé náà jẹ. 3Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, jẹ ìwé tí a ká, tí mo fún ọ yìí, kí o sì yó.” Mo bá jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi.#Ifi 10:9-10
4Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, lọ bá àwọn ọmọ Israẹli kí o sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn. 5Kì í sá ṣe àwọn tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí ó ṣòro gbọ́, ni mo rán ọ sí, àwọn ọmọ ilé Israẹli ni. 6N kò rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí yóo ṣòro fún ọ láti gbọ́. Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ irú wọn ni mo rán ọ sí, wọn ìbá gbọ́ tìrẹ. 7Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò ní gbọ́ tìrẹ, nítorí pé wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Olóríkunkun ati ọlọ́kàn líle ni gbogbo wọn. 8Mo ti mú kí ojú rẹ le sí tiwọn. 9Bí òkúta adamanti ṣe le ju òkúta akọ lọ ni mo ṣe mú kí orí rẹ le ju orí wọn lọ. Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí ojú wọn já ọ láyà, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”
10Ó tún sọ fún mi, pé, “Ọmọ eniyan, fi etí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí n óo bá ọ sọ, kí o sì fi wọ́n sọ́kàn. 11Lọ bá àwọn eniyan rẹ tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, kí o sọ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ fún wọn; wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má sì gbọ́.”
12Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, mo sì gbọ́ ìró kan lẹ́yìn mi tí ó dàbí ariwo ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá, ó ní, “Ẹ fi ìyìn fún ìfarahàn ògo OLUWA ní ibùgbé rẹ̀.” 13Ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà ni mò ń gbọ́ tí wọn ń kan ara wọn, ati ìró àgbá wọn; ó dàbí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá. 14Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, ó sì gbé mi lọ. Tìbínú-tìbínú ni mo sì fi ń lọ. Ẹ̀mí OLUWA ni ó gbé mi lọ pẹlu agbára. 15Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu.
OLUWA Yan Isikiẹli Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣọ́
(Isi 33:1-9)
16Lẹ́yìn ọjọ́ keje, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 17“Ọmọ eniyan, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohunkohun lẹ́nu mi, o gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn. 18Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 19Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú, tí kò bá yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe, tabi ọ̀nà ibi tí ó ń tọ̀; yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ óo gba ara rẹ là.
20“Bẹ́ẹ̀ náà sì ni bí olódodo bá yipada kúrò ninu òdodo rẹ̀, tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, tí mo sì gbé ohun ìkọsẹ̀ kan siwaju rẹ̀, yóo kú, nítorí pé o kò kìlọ̀ fún un, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kò sì ní ranti iṣẹ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe; ṣugbọn n óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. 21Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún olódodo náà pé kí ó má dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè, nítorí pé ó gbọ́ ìkìlọ̀; ìwọ náà yóo sì gba ẹ̀mí ara rẹ là.”
Isikiẹli yóo Ya Odi
22Ẹ̀mí OLUWA sì wà lára mi, ó sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni n óo ti bá ọ sọ̀rọ̀.”
23Mo bá dìde, mo jáde lọ sí àfonífojì. Mo rí ìfarahàn ògo OLUWA níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí i lẹ́bàá odò Kebari, mo bá dojúbolẹ̀. 24Ṣugbọn ẹ̀mí Ọlọrun kó sí mi ninu, ó sì gbé mi nàró; ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé, “Lọ ti ara rẹ mọ́ ilé rẹ. 25Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! A óo na okùn lé ọ lórí, a óo sì fi okùn náà dè ọ́, kí o má baà lè jáde sí ààrin àwọn eniyan. 26N óo mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ ọ lẹ́nu kí o sì ya odi, kí o má baà lè kìlọ̀ fún wọn, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn. 27Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.”

Currently Selected:

ISIKIẸLI 3: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy