YouVersion Logo
Search Icon

TẸSALONIKA KEJI 3

3
Ẹ Gbadura fún Wa
1Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbadura fún wa, pé kí ọ̀rọ̀ Oluwa lè máa gbilẹ̀, kí ògo rẹ̀ máa tàn sí i, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láàrin yín. 2Kí ẹ tún máa gbadura pé kí Ọlọrun gbà wá lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn ìkà, nítorí kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó gbàgbọ́.
3Ṣugbọn olódodo ni Oluwa, òun ni yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóo sì pa yín mọ́ kúrò ninu ibi gbogbo. 4A ní ìdánilójú ninu Oluwa nípa yín pé àwọn ohun tí a ti sọ, tí ẹ sì ń ṣe, ni ẹ óo máa ṣe.
5Oluwa yóo tọ́ ọkàn yín láti mọ ìfẹ́ Ọlọrun ati ohun tí Kristi faradà nítorí yín.
Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Onímẹ̀ẹ́lẹ́
6Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa. 7Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bí ó ti yẹ kí ẹ ṣe àfarawé wa, nítorí a kò rìn ségesège nígbà tí a wà láàrin yín. 8Bẹ́ẹ̀ ni a kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni ninu yín lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣugbọn ninu làálàá ati ìṣòro ni à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára. 9Kì í ṣe pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹun lọ́dọ̀ yín; ṣugbọn a kò ṣe bẹ́ẹ̀ kí á lè fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fun yín, kí ẹ lè fara wé wa. 10Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a pàṣẹ fun yín pé bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò ṣiṣẹ́, ẹ má jẹ́ kí ó jẹun.
11Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri. 12A pàṣẹ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a tún ń rọ̀ wọ́n ninu Oluwa Jesu Kristi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ fún oúnjẹ ti ara wọn.
13Ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí rere su yín í ṣe. 14Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ninu ìwé yìí, ẹ wo irú ẹni bẹ́ẹ̀ dáradára. Ẹ má ṣe bá a da nǹkankan pọ̀, kí ó lè yí pada. 15Ẹ má mú un lọ́tàá, ṣugbọn ẹ máa gbà á níyànjú bí onigbagbọ.
Gbolohun Ìparí
16Kí Oluwa alaafia fúnrarẹ̀ fun yín ní alaafia nígbà gbogbo lọ́nà gbogbo. Kí Oluwa wà pẹlu gbogbo yín.
17Èmi Paulu ni mò ń fi ọwọ́ ara mi pàápàá kọ ìwé yìí. Bí èmi ti máa ń kọ̀wé nìyí.
18Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín.

Currently Selected:

TẸSALONIKA KEJI 3: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy