YouVersion Logo
Search Icon

KRONIKA KEJI 3

3
1Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹmpili OLUWA ní Jerusalẹmu, níbi ìpakà Onani, ará Jebusi, lórí òkè Moraya, níbi tí OLUWA ti fi ara han Dafidi, baba rẹ̀; Dafidi ti tọ́jú ibẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. 2Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà ní ọjọ́ keji oṣù keji ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. 3Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọrun tí Solomoni fi lélẹ̀ gùn ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). 4Yàrá kan wà ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní ọgọfa igbọnwọ (mita 54), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ déédé ìbú tẹmpili. 5Ó yọ́ ojúlówó wúrà bo gbogbo inú rẹ̀. Ó fi igi sipirẹsi tẹ́ gbogbo inú gbọ̀ngàn rẹ̀. Ó sì yọ́ wúrà dáradára bò ó lórí, ó ya igi ọ̀pẹ ati ẹ̀wọ̀n, ó fi dárà sórí rẹ̀. 6Ó fi òkúta olówó iyebíye ṣe iṣẹ́ ọnà sára ilé náà, wúrà tí ó rà wá láti ilẹ̀ Pafaimu ni ó lò. 7Ó yọ́ wúrà bo gbogbo igi àjà ilé náà patapata, ati àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, ògiri rẹ̀ ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fi àwòrán àwọn kerubu dárà sí ara àwọn ògiri. 8Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé ìbú tẹmpili náà, ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9). Ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó yọ́ ìwọ̀n ẹgbẹta (600) talẹnti ojúlówó wúrà, ó fi bo gbogbo inú rẹ̀. 9Aadọta ìwọ̀n ṣekeli wúrà ni ó fi ṣe ìṣó, ó sì yọ́ wúrà bo gbogbo ara ògiri yàrá òkè. #Jẹn 22:22 #Eks 26:33-34
10Ó fi igi gbẹ́ kerubu meji, ó yọ́ wúrà bò wọ́n, ó sì gbé wọn sí ibi mímọ́ jùlọ. 11Gígùn gbogbo ìyẹ́ kerubu mejeeji jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni keji jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ìyẹ́ rẹ̀ keji tí òun náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), nà kan ìyẹ́ kerubu keji. 12Ekinni ninu àwọn ìyẹ́ kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, ó nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji, ìyẹ́ rẹ̀ keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, òun náà nà kan ìyẹ́ ti kerubu kinni. 13Àwọn kerubu yìí dúró, wọ́n kọjú sí gbọ̀ngàn ilé náà; gígùn gbogbo ìyẹ́ wọn jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). 14Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ti àlàárì ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ ìbòjú fún ibi mímọ́ jùlọ, ó sì ya àwòrán kerubu sí i lára. #Eks 25:18-20 #Eks 26:31
Àwọn Òpó Idẹ Meji
(1A. Ọba 7:15-22)
15Ó ṣe òpó meji sí iwájú ilé náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ga ní igbọnwọ marundinlogoji (mita 15). Ọpọ́n orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ga ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un (mita 2¼). 16Ó ṣe àwọn nǹkankan bí ẹ̀wọ̀n, ó fi wọ́n sórí àwọn òpó náà. Ó sì ṣe ọgọrun-un (100) èso pomegiranate, ó so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà. 17Ó gbé àwọn òpó náà kalẹ̀ níwájú tẹmpili, ọ̀kan ní ìhà àríwá, wọ́n ń pè é ní Jakini, ekeji ní ìhà gúsù, wọ́n ń pè é ní Boasi.

Currently Selected:

KRONIKA KEJI 3: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy