Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ ÌsìnÀpẹrẹ

Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ Ìsìn

Ọjọ́ 6 nínú 7

Máṣe Sọ Àrà Rẹ Nu 2

Ọrọ Itoni meta Pàtàkì ti a fún wa níbí ni lati ran wa lọwọ bi onigbagbọ to'n gbìyànjú láti gbé igbeaye ìrúbọ ati lati mú iṣẹ ìsìn Kirisiteni ṣe, fún ìlera émi rẹ máṣe ri àrà rẹ bi ẹni tó kọja itoni oro Ọlọrun, nitori ayē gíga to wa ni ará Kristi.

Lákọkọ́, ni ìpín nínú ayọ ati ẹkun ẹlomiran; jẹ onínúure àti alábàkẹdun. Awọn iṣẹlẹ yii kólé sa láì ma wáyé ṣugbọn ṣe ará rẹ ni ẹni afẹ ati ẹni ìtùnú, ìwà méjèèjì yi jẹ ìwà bi Ọlọrun.

Èkejì, máà gbé ni irẹpọ̀ pẹlu awọn onigbagbo ìyókù láì jẹ onigberaga ọkan, ọlọkàn gíga àti ati enitó dáwà. Jẹ onírẹlẹ ọkàn, ṣetan lati fi àrà rẹ fún iṣẹ́ ìrẹlẹ, yẹra lati jẹ onidarudapọ ati gbigbe ará rẹ ga.

Ni ìparí, máṣe fí ayé gbá ero igbẹsan, fi gbogbo ipò ungbe fún irú ìgbésẹ lati gbẹsan rúbọ ṣugbọn sà ipá láti gbé igbeaye òdodo bi àpẹrẹ níwájú awọn ẹlòmíràn.

Pípa awọn itọni yii mọ yíò ran ọ lọwọ láti mú ìgbéraga walẹ, mú ọ jẹ onírẹlẹ ọkàn ati onitẹriba.

Kika siwaju: Galatia 6:3, Owe 3:7, Owe 20:22

Adura: OLUWA, mo gba itọni rẹ lóni lati ma gbé nínú wọn.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ Ìsìn

Igbe Ayé Kristeni kii ṣe ìgbé Ayé irọrun, ọrọ àti itẹlọrun ní gbogbo ìgbà ṣugbọn ojẹ ìgbé Ayé Ìrúbọ ati ìsìn. Jésù wá sí ayé láti wá fi àpẹẹrẹ náà hàn fún wa láti ri. Jésù wá, o gbè ìgbé Ayé isẹrà ẹni, aimọtàrà ẹni nikan, iyasọtọ, iwọntunwọnsi ati ìrúbọ titi ti O fi kù fún ìràpadà wá. Ìdí yii ni àfi ni àkọsílẹ̀ rẹ ninú awọn ìwé ìhìnrere.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL