Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ ÌsìnÀpẹrẹ

Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ Ìsìn

Ọjọ́ 4 nínú 7

Ṣe Pẹlú Ìfẹ

Yíò ṣòro látí gbé igbeaye ìrúbọ ati iṣẹ-Ìsìn láì sí ìfẹ. Ìfẹ ni èpò àgbàrá fún ìrúbọ ati iṣẹ-ìsin ton mu ati ṣe wọn rọrùn láì reti èrè nínú ṣíṣe wọn ti èrè bá tilẹ wa.

Awọn ẹsẹ ẹkọ tóní fi ìfẹ hàn ni àárin gbungbun, Ọlọrun Bàbà fún wa ni Ọmọ bibi Rẹ kan ṣoṣo nínú ìfẹ, Jésù fi ẹmi rẹ le'lẹ fún ìràpadà wá nínú ìfẹ. O gbà ìfẹ tí Ọlọ́run, ani ọpọlọpọ rẹ láti gbé igbeaye ìrúbọ ati lati sìn ará Kristi.

Ìfẹ rẹ ni lati jẹ ìfẹ tòótọ laísì àgabagebe, ìfẹ akopọ; iferan gbogbo onigbagbọ gẹgẹbi ìdílé kan ṣoṣo nínú Kristi láì wò iyatọ orúkọ ìjọ, orilẹ-ède tàbí ẹya

Kika siwaju: Johannu 3:16, Johannu 15:12-13, Matteu 5:43-46

Adura: OLÚWA, jẹki ìfẹ Rẹ jẹ mi rún nínú ohun gbogbo ti mọ bá ṣe ni orúkọ Jésù.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ Ìsìn

Igbe Ayé Kristeni kii ṣe ìgbé Ayé irọrun, ọrọ àti itẹlọrun ní gbogbo ìgbà ṣugbọn ojẹ ìgbé Ayé Ìrúbọ ati ìsìn. Jésù wá sí ayé láti wá fi àpẹẹrẹ náà hàn fún wa láti ri. Jésù wá, o gbè ìgbé Ayé isẹrà ẹni, aimọtàrà ẹni nikan, iyasọtọ, iwọntunwọnsi ati ìrúbọ titi ti O fi kù fún ìràpadà wá. Ìdí yii ni àfi ni àkọsílẹ̀ rẹ ninú awọn ìwé ìhìnrere.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL