Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ ÌsìnÀpẹrẹ

Máṣe Sọ Àrà Rẹ Nu 1
Bi o tin ṣiṣe ìsìn nínú ìjọ rẹ agbègbè rẹ àti ni arà kristi afojusun rẹ kó gbọdọ Kúrò lórí irin ìgbàgbọ rẹ àti idagbasoke nínú iwa bi Ọlọrun.
O ṣe pàtàkì kiõ má sọnu sínú ọpọ iṣẹ tó lè mú ọ pàdánù ibojuto ọkàn rẹ. Sá gbogbo ipá láti mú ifọkansin rẹ duro, ibaṣepọ pẹlú Ọlọrun, ṣiṣe àṣàrò nínú ọrọ Rẹ ati àkókò ádùrá.
Ṣíṣe awọn ohun àkọkọ ni yíò ran ọ lọwọ gidigidi nínú itẹsiwaju lati màa mu ireti, sùúrù ati ifarada rẹ dàgbà nínú gbogbo iriri, o gbọdọ ma ṣe eléyìí déédé ti o bá fẹ́ tayọ nínú isẹ isin rẹ bi kristeni.
Ṣé ifọkansin rẹ pẹlú Ọlọrun ni pàtàkì máṣe ṣáà ti. Ni ipari, àgbà ọ níyànjú lati kópa nínú bibá àìní àwọn àyànfẹ́ pàdé lati ṣe olugbalejo, kiyesii pé eléyìí jẹ ònà sí ijèrè ọkàn ati ìrinṣẹ lati ba àìní ẹlomi pàdé.
Kika siwaju: Matteu 25:35-40, Iṣe 4:32-35
Adura: OLUWA rán mi lọwọ kín má pàdánù àrà mi àti lati bojuto irin mi pẹlu Rẹ
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Igbe Ayé Kristeni kii ṣe ìgbé Ayé irọrun, ọrọ àti itẹlọrun ní gbogbo ìgbà ṣugbọn ojẹ ìgbé Ayé Ìrúbọ ati ìsìn. Jésù wá sí ayé láti wá fi àpẹẹrẹ náà hàn fún wa láti ri. Jésù wá, o gbè ìgbé Ayé isẹrà ẹni, aimọtàrà ẹni nikan, iyasọtọ, iwọntunwọnsi ati ìrúbọ titi ti O fi kù fún ìràpadà wá. Ìdí yii ni àfi ni àkọsílẹ̀ rẹ ninú awọn ìwé ìhìnrere.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL









