Láì Ṣe Àníyàn OhunkóhunÀpẹrẹ

Ẹ Máa Ṣe Àṣàrò Lórí Àwọn Nǹkan Wọ̀nyí
Ìmọ̀ràn tí ó kẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù fún ni lórí àníyàn ni pé kí a máa ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ Ọlọ́run. Ní èdè míràn, yan ohun tí o máa ronú lé lórí. Fi ojú inú wo bí o ṣe máa ń rí lára rẹ ní ìgbà tí o bá ń ronú, bíi ìgbà tí àwon ọkọ̀ òfurufú bá ń fò ní ojú ọ̀run ní pápákọ̀ òfurufú kan tí ó kún fún èrò. Ìwọ ni alábòójútó ọkọ̀ òfurufú ní pápákọ̀ òfurufú yẹn. Ìwọ ni o máa pinnu àwọn èrò tí o máa ní àti èyí tí o máa fi sílẹ̀. Ṣé o fẹ́ ní ayọ̀ ní ọ̀la? Jẹ́ kí èrò ayọ̀ dé ní ònìí. Ṣé o fẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́ ní ọ̀la? Jẹ́ kí èrò ẹ̀bi, àníyàn, àti ìbẹ̀rù kó sí ọ ní orí ní ònìí.
Ìwòsàn ní ọwọ́ ìdààmú ọkàn gba ìrònú ní ọ̀nà tí ó yẹ. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe ìpèníjà rẹ ni ìpèníjà tí o ní; bí ìwọ fúnra rẹ ṣe ń ronu nípa ìpèníjà rẹ ni ìpèníjà tí o ní. Bákan náà, ìṣòro rẹ kì í ṣe ìṣòro rẹ gan gan; ọ̀nà tí o gbà ń wo ìṣòro náà ni ìṣòro rẹ. Sátánì mọ̀ bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tí ó fi ń wá ọ̀nà láti gbin irọ́ sí inú ìrònú rẹ. Ó fẹ́ yí ojú tí o fi ń wo àwọn ìṣòro rẹ àti àìdánilójú tí o ní padà. Àmọ́ rántí pé kì í ṣe òun ni ó ń darí èrò inú rẹ.
Síwájú sí i, o ní agbára tí kò lè borí láé, nítorí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ. Ní ìgbà tí àníyàn bá fẹ́ mú kí ọkàn-àyà rẹ sorí kọ́, o lè ké pe Ọlọ́run. Èyí ni ó máa fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ọ̀daràn náà, tí ó sì máa mú un lọ sí iwájú Ẹni tí ó ní gbogbo ọlá àṣẹ. Èyí ò ní jẹ́ kí àníyàn àti ìbẹ̀rù ní ipa lórí èrò rẹ. Èyí á máa dá ààbò bo èrò rẹ bí o ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tí ó jẹ́ Bàbá rẹ.
Sùgbọ́n wíwí àti ṣíṣe èyí jẹ́ nǹkan méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. O lè pinnu pé àwọn ohun tí ó jẹ́ òtítọ́, tí ó ní ọlá, tí ó sì tọ́ nìkan ni ìwọ á máa ronú lé lórí ní ònìí. . . kódà bí ó bá tiẹ̀ gba ẹ̀mí rẹ. Àmọ́ ta ni ó lè ṣe èyí?
Ọ̀nà kan tí ó rọrùn wà tí o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ni pé kí o pinnu láti rọ̀ mọ́ Kristi. Dúró nínú rẹ̀. Wá ọ̀dọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi orísun okun rẹ àti Ẹni tí ó yẹ kí o máa ronú lé lórí. Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Máa gbọ́ ìwàásù. Máa sìn-ín. Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà, kí o sì wá àyè fún-un. Mọ̀ pé tí o bá rí nǹkan rere kan ní ìgbésí ayé rẹ, òun ni ó máa jẹ́ kí o mọ̀-ọ́n.
Ojúṣe pàtàkì tí ọmọ ẹ̀yìn ní ni pé kí ó rọ̀ mọ́ Jésù. Tí o bá sì rọ̀ mọ́ Jésù, ìwọ á fi òtítọ́ Ọlọ́run kún inú ọkàn rẹ. O máa sọ àwọn ọ̀tá di aláìníjàánu, o sì máa mú kí wọ́n máa ṣe àníyàn. O gba òtítọ́ Ọlọ́run. Òtítọ́ yìí ni ó sì ń sọ ọ di òmìnira—òmìnira kúrò nínú ìbẹ̀rù, òmìnira kúrò nínú ojo, àti pé, bẹ́ẹ̀ ni, òmìnira kúrò nínú àníyàn.
Tí o bá ń ṣe àníyàn, èyí fi hàn pé ènìyàn ni ẹ́. Kò túmọ̀ sí pé o kò ní ìmọ̀lára tí ó yẹ, o jẹ́ òmùgọ̀, o ní ẹ̀mí èṣù, tàbí pé o jẹ́ aláìpé. Kì í ṣe pé àwọn òbí rẹ ti já ọ kulẹ̀ tàbí pé o já àwọn òbí rẹ kulẹ̀. Èyí sì ṣe pàtàkì, kò túmọ̀ sí pé o kì í ṣe Kristẹni. Bẹ́ẹ̀ ni o, àní àwọn Kristẹni pàápàá máa ń ṣe àníyàn. Jésù alára kojú àníyàn nínú ọgbà Gẹtisémánì. Àmọ́, kò gbé nínú àníyàn ṣáá. Ìwọ náà ò sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.
Ọjọ́ tuntun kan ń dúró dè ọ́. Àkókò tuntun kan nínú èyí tí ìwọ á máa ṣe àníyàn díẹ̀, tí ìwọ á sì máa gbẹ́kẹ̀lé síi. Àkókò tí ìbẹ̀rù dín kù, tí ìgbàgbọ́ sì túbọ̀ ní agbára sí i. Ǹjẹ́ o lè fi ojú inú wo ìgbésí ayé kan tí kò ní sí àníyàn kankan?
Ọlọ́run lè ṣe é. Àti pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ìwọ yóò rí i.
Dáhùn
Báwo ni òye tí o ní nípa ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi ọba aláṣẹ lórí àwọn ìṣòro rẹ ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa ronú nípa àwọn ohun rere? Ìgbà wo ní ó ti nira fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Kí ni ó túmọ̀ sí fún ọ láti tẹ ojú mọ́ Jésù? Báwo ni ṣíṣe èyí ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí èrò inú rẹ wà ní abẹ́ ìṣàkóso Kristi kí o sì máa ṣe ìgbọràn sí i?
Kí ni o lè ṣe ní ìgbà míràn tí àníyàn bá fẹ́ gba ọkàn rẹ àti èrò inú rẹ?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Òǹkọ̀wé tí ó gbajúgbajà nì, Max Lucado ṣe àyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe ṣ'aáyan àníyàn ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí ì nínú ìwé Fílípì 4:4-8. Bí ọ ṣe ń tẹ̀lé ìlànà yìí – ṣíṣe àjọyọ̀ dídára Ọlọ́run, bíbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, yíyọ̀ọ̀ǹda gbogbo àkókáyà rẹ fún Ùn, àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tí ó dára – ìwọ yíó ní ìrírí àlááfìa Ọlọ́run. Bí ànìyàn ṣíṣe ṣe jẹ́ ara ìgbé-ayé, ìyẹn kò ní pé kí ó jọba lórí ayé rẹ
More