Láì Ṣe Àníyàn OhunkóhunÀpẹrẹ

Ẹ Jẹ́ Kí Ìpamọ́ra Yín Di Mímọ̀ Fún Gbogbo Ènìyàn
Ìkáyàsókè tí a kò bá kápá lè yọrí sí ìbínú kíkorò, ẹ̀sùn àìronú jinlẹ̀, àti ìgbẹ̀san gbígbóná janjan lòdì sí àwọn tó bá wà ní ọ̀nà rẹ tí wọ́n jẹ́ aláìyẹ ènìyàn tí ó jẹ́ pé ibi tí kò tọ́ ni wọ́n wà ní àkókò tí kò tọ́. Ènìyàn mélòó ló ti fara pa nítorí irú hílàhílo tí kò ṣeé kápá bẹ́ẹ̀? Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, àjálù mélòó ló ti ré kọjá nítorí pé ẹnì kan pinnu láti ṣe pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́?
Ìwà tútù yìí ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé, "Ẹ jẹ́ kí ìpamọ́ra yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn" (Fílípì 4:5 NIV). Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a túmọ̀ sí ìwà tútù ṣe àpèjúwe ìhùwàsí tí ó bojú mú ti o si dúró deedee. Ó jẹ́ ìwòye ìwà tí ó bá ìgbà náà mu, oní-sùúrù ènìyàn, tí kì í sì í bínú sódì. Ìwà pẹ̀lẹ́ ni pé kí ènìyàn dúró ṣinṣin, kó má ṣe jẹ́ alárìíwísí, kó sì jẹ́ ẹni tí ó dúró déédéé
Jésù ṣè ìlérí pé: "Nínú ayé, ẹ óò ní ìpọ́njú" (Jòhánù 16:33 NIV). Ó jẹ́ àìlè-yẹrafún tí ó dájú bí ìgbà tí oòrùn bá yọ ní òwúrọ̀, bí ìgbà tí ìgbì òkun bá ya lu bèbè òkun. Ṣùgbọ́n ohun tí ó tún yẹ kí ó rántí ni pé Jésù ti ṣè ìlérí pé Òun yíò wà pẹ̀lú rẹ nínú àwọn wàhálà wọ̀nyẹn tí ó dojú kọ ọ́. Kí Jésù tó kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́hin Rẹ̀ pé: "Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Àti dájúdájú, mo wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, títí dé òpin aye" (Mátíù 28:19-20 NIV).
Ní ododo, léraléra ni Ọlọ́run ṣè ìlérí jákèjádò nínú Bíbélì pé Òun yíò wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn Òun. Ó wà pẹ̀lú Ábúrámù nígbà tí ó ń rìn ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ tuntun kan. Ó wà pẹ̀lú Hágárì nígbà tí ó sá lọ sínú aginjù, ó sì wà pẹ̀lú Ísákì nígbà tí wọ́n fipá mú un láti má se ṣí láti ibì kan lọ sí ibòmíràn. Ó wà pẹ̀lú Jóṣúà nígbà tí ó bá àwọn ará Kénáánì jà, ó sì wà pẹ̀lú Dáfídì nígbà tí ó bá àwọn Filístínì jà. Ó wà pẹ̀lú Pétérù nínú ọgbà iẹ̀wọ̀n, ó sì wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù nígbàkigbà àti níbikíbi tó bá wà nínú ìbẹ̀rù-bojo.
Ọlọ́run kò fi ìgbà kankan tá kété sí wọn. Ní pàtó, orúkọ rẹ̀ gan-an ni Immanueli, èyí tí ó túmọ̀ sí "Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa". Ó di ènìyàn. Ó di ẹ̀ṣẹ̀. Ó ṣẹ́gun ipò òkú. Ó sì wà pẹ̀lú rẹ.
Bóyá ṣe ni oń gbìyànjú láti jẹ ki ìdílé kan fi ẹsẹ múlẹ̀, kí òwò kan má bàa bọ́ sí omi tàbí kí ilé ẹ̀kọ́ kan má bàa pa run lo ń bá yí lónìí. Ọ̀nà tí ó bá gbà kojú ìṣòro náà ló máa fi ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé hàn. Tí o bá gbẹ́kẹ̀lé Jésù, tí ó sì gbà gbọ́ pé ó wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo, tí ó bá jẹ́ kó máa darí rẹ, ọkàn rẹ á balẹ̀, ìwọ a sì máa gbé ìgbé ayé tó ní ìtumọ̀. Ìfọ̀kànbalẹ̀ yii yíò jẹ ki o rii bi Ọlọrun ṣe n ṣiṣẹ ni ipo rẹ — ati pe awọn miiran yíò ṣe akiyesi pe nkankan wa ti o yatọ nínú ayé rẹ. Yíò mú àníyàn rẹ kúrò, yíò mú kí ìgbàgbọ́ rẹ dàgbà sì, yíò sì jẹ́ kí áwọn ẹlòmíràn mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ olótítọ́ nígbà gbogbo.
Ńṣe ni àbójútó ìfòyà dà bí ìgbà tí ènìyàn bá fà àgékù igi jáde nínú ilẹ̀. Àwọn àníyàn rẹ kan ti ta gbòǹgbò gan-an, ó sì máa ń ṣòro láti fà wọ́n tu. Ṣùgbọ́n ìwọ nìkan kò lè dá se. Fi ìpèníjà rẹ sì iwájú Baba rẹ, kí o sì bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Se Ó máa yanjú ọ̀ràn náà? Bẹ́ẹ̀ ni, yíò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ṣé Ó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́gán? Ó ṣeé ṣe. Tàbí kó jẹ́ pé ìdánwò ni ó jẹ́ ní apá kan láti kọ́ ẹ̀kọ́ lati máa mú sùúrù. Èyí tí ó dájú púpọ̀ ni pé: Ìfarabàlẹ̀ tí ó ń ranni lè sún ọ dé ibi pé ìwọ yíò yí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Fèsì
Tani ni igbe ayé rẹ ni ó ni ipa julọ ni ọna ti o gba dá sí ìnira?
Báwo lo ṣe máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà ìwà tútù? Ṣé ó lè sọ pé bí o ṣe máa ń ṣe sí áwọn ènìyàn nígbà tí wọ́n bá wá ní ipò inira dà bí oníwà tútù? Kíni ìdí tàbí kínì kò fi jẹ ìdí tí kò fi rí bẹ́ẹ̀?
Báwo ni pé bí ó ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìpamọ́ra tí ó ń tàn káàkiri?
Ẹ Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ìfòyebánilò Yín Di Ohun Tí Gbogbo Ènìyàn Lè Rí
Ìdààmú tí a kò bá kápá lè yọrí sí ìbínú kíkorò, ẹ̀sùn àìronú jinlẹ̀, àti ìgbẹ̀san gbígbóná janjan lòdì sí àwọn tó bá wà ní ọ̀nà rẹ tí ó jẹ́ pé ibi tí kò tọ́ ni wọ́n wà ní àkókò tí kò tọ́. Èèyàn mélòó ló ti fara pa nítorí irú wàhálà tí kò ṣeé kápá bẹ́ẹ̀? Àmọ́ ṣá o, àjálù mélòó ló ṣeé yẹra fún nítorí pé ẹnì kan pinnu láti jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́?
Ìwà tútù yìí ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé, "Ẹ jẹ́ kí ìwà tútù yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn" (Fílípì 4:5 NIV). Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ìwà tútù ó túmọ̀ sí pé ẹni náà ti dàgbà nípa tẹ̀mí. Ó ń tọ́ka sí ìwà tó bá ipò náà mu, èyíinì ni pé kéèyàn jẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin, tí kì í sì í bínú sódì. Ìwà pẹ̀lẹ́ ni pé kéèyàn dúró gbọn-in, kó má ṣe jẹ́ alárìíwísí, kó sì jẹ́ onídàájọ́ òdodo.
Jésù ṣèlérí pé: "Nínú ayé, ẹ óò ní ìpọ́njú" (Jòhánù 16:33 NIV). Ó dájú bí ìgbà tí oòrùn bá yọ ní òwúrọ̀, bí ìgbà tí ìgbì òkun bá ya lu etíkun. Àmọ́ ohun tó tún yẹ kó o rántí ni pé Jésù ti ṣèlérí pé òun á wà pẹ̀lú rẹ nígbà ìṣòro. Kí Jésù tó kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: "Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. dájúdájú, mo wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, títí dé òpin ètò àwọn nǹkan" (Mátíù 28:19-20 NIV).
Kódà, léraléra ni Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì pé òun á wà pẹ̀lú àwọn èèyàn òun. Ó wà pẹ̀lú Ábúrámù nígbà tó ń rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ tuntun kan. Ó wà pẹ̀lú Hágárì nígbà tó sá lọ sínú aginjù, ó sì wà pẹ̀lú Ísákì nígbà tí wọ́n fipá mú un láti máa ṣí láti ibì kan lọ sí ibòmíràn. Ó wà pẹ̀lú Jóṣúà nígbà tó bá àwọn ará Kénáánì jà, ó sì wà pẹ̀lú Dáfídì nígbà tó bá àwọn Filísínì jà. Ó wà pẹ̀lú Pétérù nínú ẹ̀wọ̀n, ó sì wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù nígbàkigbà àti níbikíbi tó bá wà nínú ipò lílekoko.
Ọlọ́run kì í wo nǹkan látọ̀nà jíjìn. Kódà, orúkọ rẹ̀ gan-an ni Immanuel, èyí tó túmọ̀ sí "Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa". Ó di èèyàn. Ó di ẹ̀ṣẹ̀. Ó ṣẹ́gun sàréè. Ó sì ṣì wà pẹ̀lú rẹ.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ dídáàbò bo ìdílé kan, kí òwò kan má bàa bọ́ sójú omi tàbí kí ilé ẹ̀kọ́ kan má bàa pa run lo ń bá yí lónìí. Ọ̀nà tó o bá gbà kojú ìṣòro náà ló máa fi ẹni tó o gbẹ́kẹ̀ lé hàn. Tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jésù, tó o sì gbà gbọ́ pé ó wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo, tó o bá jẹ́ kó máa darí rẹ, ọkàn rẹ á balẹ̀, wàá sì máa gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀. Ifarabalẹ yii yoo jẹ ki o rii bi Ọlọrun ṣe n ṣiṣẹ ni ipo rẹ - ati pe awọn miiran yoo ṣe akiyesi pe nkankan ti o yatọ nipa rẹ. Yóò mú àníyàn rẹ kúrò, yóò mú kí ìgbàgbọ́ rẹ dàgbà, yóò sì jẹ́ káwọn ẹlòmíràn mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́ nígbà gbogbo.
Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá ń yọ igi kan jáde nínú ilẹ̀. Àwọn kan lára àwọn àníyàn rẹ ti ta gbòǹgbò gan-an, ó sì máa ń ṣòro láti mú wọn kúrò. Ṣùgbọ́n o kò ní láti ṣe é nìkan. Sọ ìṣòro náà fún Bàbá rẹ, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Ǹjẹ́ ó máa yanjú ọ̀ràn náà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé ó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà lójú ẹsẹ̀? Ó ṣeé ṣe. Tàbí kó jẹ́ pé apá kan ìdánwò náà ni pé kí wọ́n máa mú sùúrù. Ohun kan tó dájú ni pé: Ìbàlẹ̀ ọkàn tó ń ranni á máa bá a lọ bó o bá ṣe ń bá a sọ̀rọ̀.
Dáhùn
Àwọn wo ló máa ń múnú bí ẹ tó o bá wà nínú ipò tí kò bára dé?
Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ náà ìwà tútù? Ṣé wàá sọ pé bó o ṣe máa ń ṣe sáwọn èèyàn nígbà tí wàhálà bá dé máa ń dà bí oníwà tútù? Kí nìdí tàbí kí nìdí tí kò fi rí bẹ́ẹ̀?
Báwo ni mímọ̀ tó o mọ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn?
Nípa Ìpèsè yìí

Òǹkọ̀wé tí ó gbajúgbajà nì, Max Lucado ṣe àyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe ṣ'aáyan àníyàn ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí ì nínú ìwé Fílípì 4:4-8. Bí ọ ṣe ń tẹ̀lé ìlànà yìí – ṣíṣe àjọyọ̀ dídára Ọlọ́run, bíbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, yíyọ̀ọ̀ǹda gbogbo àkókáyà rẹ fún Ùn, àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tí ó dára – ìwọ yíó ní ìrírí àlááfìa Ọlọ́run. Bí ànìyàn ṣíṣe ṣe jẹ́ ara ìgbé-ayé, ìyẹn kò ní pé kí ó jọba lórí ayé rẹ
More