Láì Ṣe Àníyàn OhunkóhunÀpẹrẹ

Máa Yọ̀ Nínú Olúwa Ní Îgbà Gbogbo
Ìdààmú ọkàn kì í ṣe ohun tí ènìyàn lè retí pé ó lè ṣẹlẹ̀. Bí mi ò bá ṣe òwò náà ńkọ́? Tí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò lówó láti ra ẹ̀rọ abẹ fún àwọn ọmọ wa ńkọ́? Bí àwọn ọmọ mi bá ní eyín tí kò gún régé ńkọ́? Tí ó bá jẹ́ pé eyín wọn tí ó ti là kò jẹ́ kí wọ́n lè ní ọ̀rẹ́ . . . iṣẹ́ tí ó máa fún wọn ní ayọ̀ . . . tàbí kí wọ́n má lè ní ọkọ tàbí aya ńkọ́? Ìdààmú ọkàn ni gbígbé ìgbésí ayé ní ìró kékeré pẹ̀lú àwọn àníyàn ńlá.
Ǹjẹ́ àníyàn ti ba ọkàn rẹ jẹ́? Ǹjẹ́ o lè wá nǹkan ṣe sí i? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ nìkan ni ó ní irú ìṣòro yìí. Ó gba ìsapá láti borí àníyàn àti ìdààmú, àmọ́ kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pé kí o máa ṣe àníyàn ṣáá. Ọlọ́run ní ìfẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ní ó ń bó ojú tó ayé yín. Ó máa ń kíyè sí ìgbésí ayé rẹ.
Nínú Fílípì 4:4, Pọ́ọ̀lù sọ ohun tí a lè pè ní "oògùn" fún àníyàn àti ìdààmú. Ohun tí ó gba àfiyèsí ni pé, ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkésíni láti "máa yọ̀ nínú Olúwa ní ìgbà gbogbo". Pọ́ọ̀lù lo gbogbo ohun èlò inú àpótí tí ó wà nínú ẹsẹ yìí láti mú kí àwọn tí ó ń kà á pa ọkàn pọ̀. Ní àkọ̀ọ́kọ́ ná, ó lo ọ̀rọ̀-ìṣe kan kí wọ́n lè gbọ́ pé, "ẹ tẹ̀ síwájú, ẹ máa yọ̀ ní ìgbà gbogbo!" Bí ó bá sì jẹ́ pé àkókò ọ̀rọ̀ kò tó, ó yọ ọjọ́ tí ó pé: "Ẹ yọ̀ nínú Olúwa ní ìgbà gbogbo." Bíi ẹni pé ìyẹn ò tó, ó tún pàṣẹ náà sọ: "Ní èèkan si Èmi yóò sọ pé, ẹ máa yọ̀!"
Àmọ́ báwo ni o ṣe máa ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ yìí? Nípa gbígba ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi ọba aláṣẹ. Àwọn tí ó máa ń ṣe àníyàn jù lọ ni àwọn tíó máa ń fẹ́ láti máa ṣe àkóso ara wọn. Bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń gbìyànjú láti ṣe àkóso ayé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe túbọ̀ ń rí i pé àwọn kò lè ṣe àkóso rẹ̀. Ìgbésí ayé á wá dà bíi ìdààmú ọkàn ní gbogbo ọ̀nà, ìjákulẹ̀; ìdààmú ọkàn, ìjákulẹ̀; ìdààmú ọkàn, ìjákulẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí o bá mọ̀ pé ọ̀run ní ìtẹ́ kan tí àwọn ènìyàn ń gbé, ìwọ á jẹ́ kí Olúwa máa ṣe àkóso. Ọlọ́run á mú ìbẹ̀rù rẹ kúrò, kì í ṣe nípa mímú ìṣòro náà kúrò, bí kò ṣe nípa fífi agbára rẹ̀ hàn ó sì fi hàn pé òun wà pẹ̀lú rẹ. Bí o ṣe túbọ̀ ń mọ Ọlọ́run Bàbá rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àníyàn rẹ á túbọ̀ dín kù.
Ní ìgbà míràn tí o bá ń bẹ̀rù ọjọ́ iwájú, máa yọ̀ nínú ipò ọba aláṣẹ Olúwa. Máa yọ̀ nítorí ohun tí ó ti gbé ṣe. Máa yọ̀ pé ó lè ṣe ohun tí ìwọ ò lè ṣe. Máa ronú nípa Ọlọ́run nínú ọkàn rẹ. Ní ibi tí àwọn ẹlòmíràn ti ń wo àwọn ìṣòro ayé tí wọ́n sì ń fi ọwọ́ wọn gbọ̀n, wo àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn kí o sì tẹrí ba. Máa ronú nípa ọba rẹ ní ọ̀nà tí ó fi hàn pé o mọ iyì rẹ̀. Má ṣe dá orí sọ ninu awọn iṣoro rẹ. Jẹ́ kí ó dá ẹ lójú pé àwọn nǹkan rere máa ṣẹlẹ̀. Ṣe àyẹ̀wò ohun tí ó mú kí o ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, kí o sì rí i dájú pé ohun tí ó mú kí o gbà pé Ọlọ́run wà ni pé ó fi ọkàn tán ẹ.
Tún rántí pé Ọlọ́run ti dá ọ nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi àti ẹ̀dùn ọkàn tí ó lè mú kí o máa ṣe àníyàn. Ẹ̀rí ọkàn tí ó ń dá ẹni lẹ́bi tí a kò sì yanjú rẹ̀ lè sọ ọ́ di ẹni tí ó ń fi ara rẹ̀ pa mọ́, tí ó ń sá fún nǹkan, tí ó ń sẹ́, tí ó sì ń díbọ́n. Ẹ̀rí ọkàn tí ó ń dá ẹni lẹ́bi lè mú kí ọkàn rẹ bà jẹ́. Ṣùgbọ́n oore-ọ̀fẹ́ ń dá ẹ̀mí náà padà, ó sì jẹ́ kí o lè gbẹ́kẹ̀ lé ìdáríjì Ọlọ́run. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé ó ṣeé ṣe fún wa láti máa yọ̀ láì sí ìdíwọ́, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run.
Ọwọ́ Bàbá rẹ wà ní àrọ̀ọ́wọ́tó, nítorí náà fi gbogbo ọkàn rẹ lé e lọ́wọ́. Bí o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ á rí i pé ó ṣeé ṣe - bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe! - láti má ṣe àníyàn fún ohunkóhun.
Dáhùn
Báwo ni ayọ̀ ṣíṣe ṣe jẹ́ ìpinnu? Báwo ni inú dídùn nínú Olúwa ṣe rí ní ojú rẹ?
Báwo ni o ṣe máa ṣe àlàyé ìgbẹ́kẹ̀lé tí o ní pé Ọlọ́run ń darí ìgbésí ayé rẹ? Àwọn ọ̀nà wo ni o ti gbà rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé rẹ?
Báwo ni lílo àkókò ní ojoojúmọ́ ní iwájú Ọlọ́run ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa yọ̀ nínú Olúwa ní ìgbà gbogbo?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Òǹkọ̀wé tí ó gbajúgbajà nì, Max Lucado ṣe àyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe ṣ'aáyan àníyàn ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí ì nínú ìwé Fílípì 4:4-8. Bí ọ ṣe ń tẹ̀lé ìlànà yìí – ṣíṣe àjọyọ̀ dídára Ọlọ́run, bíbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, yíyọ̀ọ̀ǹda gbogbo àkókáyà rẹ fún Ùn, àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tí ó dára – ìwọ yíó ní ìrírí àlááfìa Ọlọ́run. Bí ànìyàn ṣíṣe ṣe jẹ́ ara ìgbé-ayé, ìyẹn kò ní pé kí ó jọba lórí ayé rẹ
More