Láì Ṣe Àníyàn OhunkóhunÀpẹrẹ

Anxious for Nothing

Ọjọ́ 3 nínú 5


Mú Àwọn Ẹ̀bẹ̀ Rẹ Wá Sí Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Nínú Lúùkù 18:18, Jésù sọ àkàwé kan nípa opó kan tí ó ń tẹpẹlẹ mọ́ bíbá onídàájọ́ aláìṣòdodo kan sọ̀rọ̀. Obìnrin náà ń yọ adájọ́ náà lẹ́nu gan-an débi pé ní ìkẹyìn ó gbà láti ṣe ohun tí obìnrin náà fẹ́ kí ó bàa lè lọ. Jésù parí àkàwé náà nípa sísọ pé: "Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán-tòru? (Ẹsẹ 7)

Kí lo lè sọ nípa àkàwé yìí? Ṣé onídàájọ́ tí kì í fẹ́ dáni lẹ́jọ́ ni Ọlọ́run? Ṣé ìwọ ni opó tí wọ́n pa tì náà? Ṣé o rò pé ńṣe ni àdúrà kàn ń dààmú Ọlọ́run títí tí ó fi máa gbà ẹ́? Rárá o, àfiwé tí ó fi ìyàtọ̀ hàn ni èyí, kì í ṣe ti ìfiwé. Ọlọ́run kò dà bíi onídàájọ́ inú àkàwé yẹn. Kì í lọ́ tìkọ̀ láti dáhùn àdúrà àwọn ènìyàn rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọba, o lè yí ojú sí i ní ìgbàkigbà. Kò ní sọ pé kí o dúró tàbí kí o pe òun ní ìgbà míràn. Ọlọ́run ní ìfẹ́ ohùn rẹ. Ní gbogbo ìgbà. Kì í sá pa mọ́ ní ìgbà tí o bá pè é. Ó máa ń gbọ́ àdúrà rẹ.

Àmọ́, kí ni idí tí ó fi yẹ kí o sọ ohun tí ò ń fẹ́ fún Ọlọ́run? Kí ni ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀ ní ìgbà tí ó ti mọ ohun tí o máa béèrè? Àǹfààní ni àdúrà máa ṣe fún ọ. Ó máa jẹ́ kí o lè fi ìgbàgbọ́ ṣe ohun tí o mọ̀ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Tí o bá ń gba àdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn ìṣòro tí o ní, tí o sì rí i pé ó ń dáhùn àdúrà rẹ, ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ ní agbára síi. Ìwọ á ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run á máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà, pàápàá ní àwọn àkókò tí wàhálà bá pọ̀ jù lọ.

Àdúrà jẹ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Bàbá rẹ ọ̀run. O fi àwọn àníyàn rẹ leè l'ọ́wọ́, o sì rán-an létí nípa àwọn ìlérí tí o ti ṣe nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. O rán ara rè létí pẹ̀lú. O wá ìlérí kan tí ó bá ìṣòro rẹ mu, o sì gba àdúrà l'órí rẹ̀. Àwọn àdúrà ìgbàgbọ́ wọ̀nyí kan ọkàn Ọlọ́run, wọ́n sì fi àwọn angẹli ọrun ṣí ojú iṣẹ́. A bẹ̀ẹ̀rẹ̀ síi ṣe àwọn iṣẹ iyanu. Àwọn ìrírí ìdààmú rẹ dínkù; àwọn ẹ̀bẹ̀ rẹ sì pọ̀ síi. Àwọn èrò àníyàn dínkù, àwọn èrò tí ó kún fún àdúrà sì pọ̀ síi.

Ìdúpẹ́ ni ohun tí Ọlọ́run ń lò láti ràn ọ́ lówó láti má ronú nípa ara rẹ mọ́, kí o máa ronú nípa Ọlọ́run. Ìm'oore jẹ́ ohun ìjà tí ó ní agbára tí a fi ń gbógun ti ìdààmú ọkàn nítorí pé ó ń mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ "ìbá jẹ́ pé" lọ sí àgbègbè "ó ti ṣẹ". Ọkàn tí ó ń ṣe àníyàn wí pé, "Ọlọ́run, ìbá jẹ́ pé mo bá ní èyí, ìyẹn, tàbí tọ̀hún, kò ní sí ìṣòro kankan. "Ọkàn-àyà tí ó kún fún ọpẹ́ sọ pé, "Olúwa, o ti fún mi ní èyí, ìyẹn, àti tọ̀hún. O ṣeun fún ìbùkún rẹ, Ọlọ́run."

Ìtẹ́lọ́rùn tí ó dá lórí Kristi yóò sọ ọ́ di alágbára. Ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ní ìwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè gba Kristi rẹ kúrò ní ọwọ́ rẹ, kò sí ẹni tí ó lè gba ìdùnnú rẹ lọ́wọ́ rẹ. Àìṣeyọrí kò lè gba ayọ̀ rẹ, nítorí pé Jésù tóbi ju ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lọ. Ìjákulẹ̀ kò lè gba ayọ̀ rẹ, nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwéwèé rẹ lè máà kẹ́sẹ járí, ìwéwèé Ọlọ́run máa ń kẹ́sẹ járí ní ìgbà gbogbo. Kódà ikú pàápàá kò lè gba ayọ̀ rẹ, nítorí pé Jésù ti ṣẹ́gun ikú pàápàá.

Ohun tí o ní nínú Kristi ju ohunkóhun tí o kò ní lọ. O ní Ọlọ́run, ẹni tí ó ní ìfẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, àti àwọn ọmọ ogun ọ̀run tí wọ́n ń ṣọ́ ọ, tí wọ́n sì ń dá ààbò bò ọ́. O ní ìwàláàyè Jésù nínú rẹ. Nínú Kristi o ní ohun gbogbo. Nítorí náà, jẹ́ kí ìwà Ọlọ́run wà ní ọkàn rẹ. Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní ìgbàkúùgbà tí o bá ń ṣe àníyàn, kí o sì múra sílẹ̀ de ọjọ́ kan tí o máa ní ayọ̀.

Dáhùn

Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ọ́ bíi pé ò ń da Ọlọ́run láàmú ní ìgbà tí o bá ń gba àdúrà? Báwo ni mímọ̀ tí o mọ̀ pé Ọlọ́run ń fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ṣe lè mú kí ó wù ọ́ láti bá a sọ̀rọ̀?

Irú ẹ̀mí wo ni o sábà máa ń ní nígbà tí o bá ń gba àdúrà? Báwo ni àdúrà rẹ ṣe máa yí padà tí o bá gbájú mọ́ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún ọ?

Àwọn ohun tí ó ń kó ìdààmú báni wo ni o máa gba àdúrà lé lórí ní ònìí? Báwo ni o ṣe lè máa rán ara rẹ létí bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ adúróṣinṣin ní ìgbà àtijọ́ bí o ṣe ń gba àdúrà nípa àwọn ohun tí o nílò yìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Anxious for Nothing

Òǹkọ̀wé tí ó gbajúgbajà nì, Max Lucado ṣe àyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe ṣ'aáyan àníyàn ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí ì nínú ìwé Fílípì 4:4-8. Bí ọ ṣe ń tẹ̀lé ìlànà yìí – ṣíṣe àjọyọ̀ dídára Ọlọ́run, bíbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, yíyọ̀ọ̀ǹda gbogbo àkókáyà rẹ fún Ùn, àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tí ó dára – ìwọ yíó ní ìrírí àlááfìa Ọlọ́run. Bí ànìyàn ṣíṣe ṣe jẹ́ ara ìgbé-ayé, ìyẹn kò ní pé kí ó jọba lórí ayé rẹ

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Max Lucado, HarperCollins, àti Thomas Nelson fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.thomasnelson.com/9780310087311/anxious-for-nothing-study-guide/

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ