Láì Ṣe Àníyàn OhunkóhunÀpẹrẹ

Anxious for Nothing

Ọjọ́ 4 nínú 5


Àlàáfíà Ọlọ́run Yóò Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ

Nígbà táwọn atukọ̀ òkun bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìjì kan tí kò sí atukọ̀ òkun tó lè yè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n máa ń pè é ní "ìjì paraku." Kì í ṣe pé a pèé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà tó dára, àmọ́ ó jẹ́ paraku nígbàtí a bá ṣe àkójọ oríṣiríṣi jọ. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí, irú bí ẹ̀fúùfù tó lágbára bíi ti ìjì líle àti òjò tó ń rọ̀, ló ń pa pọ̀ láti fa àjálù tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Àwọn afẹ́fẹ́ nìkan yóò jẹ́ ìpèníjà àfikún òtútù àfikún òjò? Ìyẹn ló máa ń yọrí sí àjálù.

Kò dìgbà téèyàn bá di atukọ̀ òkun kó tó lè rí ìjì líle. Kódà, kò sí àní-àní pé o ti dojú kọ àwọn kan nínú ìgbésí ayé rẹ. Ìdáwọ́ lé iṣẹ́ pẹ̀lú ìlọsíwájú. Àìsàn kan pẹ̀lú àyípadà nídìí iṣẹ́. Àjọṣepọ̀ kan tó forí ṣánpọ́n pẹ̀lú iléèwé tí ó ní kò sí ààyè. ìpàdánù òjijì pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí o kò rí tẹ́lẹ̀ tó lè ba ọjọ́ iwájú rẹ jẹ́. Ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan áwọn nǹkan wọ̀nyí lè ṣeé mójútó. Àmọ́, gbogbo wọn lápapọ̀ lágbára gan-an. Ó ti tó láti mú kí o máa rò ó pé, Ṣé màá tilẹ̀ yè é?

Ìdáhùn Pọ́ọ̀lù sí ìbéèrè yẹn jinlẹ̀ gan-an, ó sì ṣe ṣókí. Tí o bá ń sọ àwọn ẹ̀bẹ̀ rẹ fún Ọlọ́run, pẹ̀lú ope, 'àlàáfíà Ọlọ́run ... yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ' (Fílípì 4:7 NIV). Lédè mìíràn, bó o ṣe ń ṣe ipa tìrẹ tó o sì ń gbé àníyàn náà lé Ọlọ́run lọ́wọ́, òun náà á ṣe ipa tirẹ̀ nípa fífún ọ ní àlàáfíà pípé rẹ̀. Ó yẹ kó o máa ṣàníyàn . . . àmọ́ kò yẹ kó o máa ṣàníyàn. Ó yẹ kó dùn ẹ́ . . . àmọ́ ọkàn rẹ balẹ̀. Ìbàlẹ̀ ọkàn tí Ọlọ́run ń fúnni kọjá gbogbo ọgbọ́n èèyàn.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dojú kọ "ìjì líle" lójú òkun, ó sọ fún àwọn atukọ̀ náà pé, "Ní òru yìí, áńgẹ́lì Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀, tí mo sì ń sìn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì wí pé, 'Má fòyà, Pọ́ọ̀lù. . . . Ọlọ́run sì ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ nínú ọkọ̀ òkun jíǹkí rẹ'" (Ìṣe Apo 27:23-24). Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó ń rì, Ọlọ́run rán àwọn áńgẹ́lì láti wá ràn án lọ́wọ́. Ohun tí Yóò ṣe fún ìwọ náà nìyẹn. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ayé, àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ kò ní ààlà, àlàáfíà Rẹ̀ yíò ma wà títí láé.

Ó ṣeé ṣe kó o ti gbàdúrà, lọ́pọ̀ ìgbà, kó o má sì gbọ́ nǹkan kan. Má ṣe juwọ́ sílẹ̀! Jẹ́ kí òtítọ́ yìí dá ọ lójú pé bí Ọlọ́run ṣe rán àwọn áńgẹ́lì láti dáàbò bo àwọn tí ò ún kà nípa wọn nínú Bíbélì, bẹ́ẹ̀ náà ni Yóò ṣe rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti dáàbò bò ọ́ bó o ṣe ń kojú ìjì líle. Nígbà tí o fi ayé rẹ fún Un, Ó gbà ọ́ sínú ìdílé Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ó ṣeyebíye. Ó ní ète kan fún ìgbésí ayé rẹ, ó sì ń pè ọ́ pé kí o dara pọ̀ mọ́ Òun kí Ó lè mú ìfẹ́ Rè ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. Ó máa lo ìjì láti mú kí ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Rẹ̀ lágbára sí i.

Nígbà tí ẹ bá wá Olúwa, ẹ óo rí i. Nítorí náà, kọ́kọ́ wá a. Fi ìjọsìn àti ìdúpẹ́ ṣáájú. Kọ́kọ́ lọ bá Bàbá rẹ nínú àdúrà àti ìyìn. Sọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù fún un. Kóra jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀. Fi ojú rẹ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ẹ ké pe ìrànlọ́wọ́. Mọ ibi tó o kù díẹ̀ káàtó sí. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ọlọ́run bá ti gbéra, ìwọ náà gbé ìgbésẹ̀ tẹ̀lé E, kí o sì bá A rìn.

Nírètí pé Ọlọ́run ayérayé yóò jà fún ọ. Ó wà nítòsí rẹ, Ó wà nítòsí rẹ bí èémí rẹ. Ó lè máa kojú sí ìjì líle, àmọ́ Jésù fún ọ ní àlàáfíà pípé.

Fèsì

Kí ni díẹ̀ lára àwọn "ìjì líle" tí o ti dojú kọ nígbèésí ayé rẹ? Kí ni ó mú kí wọ́n ṣòro?

Àwọn ọ̀nà wo ni àlàáfíà Ọlọ́run fi yàtọ̀ sí irú àlàáfíà tí ayé lè fúnni?

Ààbò wo lo nílò látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nísinsìnyí? Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run lè bójú tó ọ ní àkókò ìjì líle koko yìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Anxious for Nothing

Òǹkọ̀wé tí ó gbajúgbajà nì, Max Lucado ṣe àyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe ṣ'aáyan àníyàn ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí ì nínú ìwé Fílípì 4:4-8. Bí ọ ṣe ń tẹ̀lé ìlànà yìí – ṣíṣe àjọyọ̀ dídára Ọlọ́run, bíbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, yíyọ̀ọ̀ǹda gbogbo àkókáyà rẹ fún Ùn, àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tí ó dára – ìwọ yíó ní ìrírí àlááfìa Ọlọ́run. Bí ànìyàn ṣíṣe ṣe jẹ́ ara ìgbé-ayé, ìyẹn kò ní pé kí ó jọba lórí ayé rẹ

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Max Lucado, HarperCollins, àti Thomas Nelson fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.thomasnelson.com/9780310087311/anxious-for-nothing-study-guide/

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ