Dìde kí o tan ìmọ́lẹ̀Àpẹrẹ

Àwọn Ọmọ Ìmọ́lẹ̀
Nínú ìwé Àìsáyà, a rí bí àwọn ènìyàn Jerúsálẹ́mù ṣe wà nínú ìdè òkùnkùn àyíká wọn àti ti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tìkalára wọn: “Nítorí náà ni ìdájọ́ òtítọ́ fi jìnnà sí wa, tí òdodo kò sì fi dé ọ̀dọ̀ wà. Ìmọ́lẹ̀ ni à ń retí, ṣugbọn òkùnkùn ló ṣú, ìtànṣán oòrùn ni à ń retí, ṣugbọn ìkùukùu ni ó bo ilẹ̀.” (Àìsáyà 59:9).
Ṣùgbọ́n ṣá, wòlíì Àìsáyà ké sí wọ́n wá sí òkè. Ó pè wọ́n sí òtítọ́.
"Dìde, Jerúsálẹ̀mù! Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ tàn fún aráyé rí. Nítorí ògo Olúwa dé láti tàn l'ára rẹ. Òkùnkùn biribiri bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ Olúwa yíó tàn sí ara rẹ, ògo Olúwa yíó sì hàn lára rẹ." (Isaiah 60:1–2)
A pé ìwọ náà sí òkè. A kò há ọ mọ́ gágá sínú òkùnkùn. Ìmọ́lẹ̀ ayé yìí sọ̀kalẹ̀ wá, Ó sì gbé ìgbé-ayé ènìyàn, lẹ́yìn èyí Ó fí ẹ̀mí Rẹ fún ọ. Òkùnkùn ayé yìí lè mu ènìyàn l'ómi. Òkúnkùn tí a máa ń dígbà bá ṣe ọ̀rẹ́ lè jọ bí ẹnipé ó dùn mọ́ ni. O lè lérò pé o kò kún ojú òṣúwọ̀n tó láti tan ìmọ́lẹ̀ Krístì. Ibi tí ọ̀tá fẹ́ dá ọ dúró sí nìyìí! Irú òkùnkùn tí àwọn tí à ń sọ nípa wọn nínú ìwé Àìsáyà há sí nìyìí. Àmọ́ ṣá, a rí Àìsáyá tí ó sọ fún àwọn ènìyàn náà kí wọ́n dìde tan ìmọ́lẹ̀.
Ọ̀rẹ́ mi, Mò ń sọ fún ọ báyìí pé, “[fi orúkọ rẹ sí ibí], dìde! Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ tàn fún arayé rí. Nítorí ògo Olúwa dé láti tàn l'ára rẹ.”
Fi ojú rẹ̀ sí ara Jésú, kí o sì jẹ́ kí Ó yí ìwòye rẹ padà. Òun ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, Ó sì fẹ́ kí o rí ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà: tí ìmọ́lẹ̀ ayé bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Àkókò tó láti dìde tan ìmọ́lẹ̀. Àkókò rèé láti dẹ́kun àti máa gbé nínú ẹ̀tàn ọ̀tá kí o sì máa gbé nínú òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àkókò tó láti dẹ́kun àti máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ara rẹ, kàkà bẹ́ẹ̀ kí o tàn ìmọ́lẹ́ sí Jésù. Àkókò tó fún ọ láti tan ìmọ́lẹ̀ Krístì kí gbogbo ayè lè rí, kí wọ́n sì mọ ògo Ọlọ́run. O lè ṣe èyí, ọ̀rẹ́ mi.
Dìde, tan ìmọ́lẹ̀.
Olúwa, mo fẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ Rẹ tàn nínú mi kí ó sì tàn jáde nínú mi. Rán mí létí òtítọ́ yìí lójoojúmọ́ pé O tóbi ju òkùnkùnkókùnkùn lọ! Àmín.
A lérò pé ètò yìí tí gbà ọ́ ní ìyànjú. Kẹ́kọ̀ọ́ síi nípa Dìde Tan Ìmọ́lẹ̀ láti ọwọ́ Allyson Golden níbí .
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ènìyàn maá ń sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé, "Kó gbogbo àníyàn rẹ tọ Ọlọ́run." Ṣé o tilẹ̀ ròó rí pé: Báwo ni mo ṣe lè ṣe èyí? Ìdíbàjẹ́ inú ayé ka 'ni l'áyà. Bí ó sì ti lè wù ọ́ tó láti tan ìmọ́lẹ̀ Jésù, ìwọ yíó máa wo òyé bí èyí yíó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ìwọ alára ń tiraka láti rí ìmọ́lẹ̀ yìí fún ara rẹ. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Jésù nígbàtí ayé tiwa gan-an dàbí pé ó wà ní òkúnkùn.
More